Babajide Sanwo-olu: Mo ti fi ọgbọ̀n ọdún ṣe iṣẹ́ púlọ́mbà

Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Twitter/Sanwo-Olu

Yoruba bọ, wọn ni ki ọrọ to o dayọ, oju a ri.

Lo difa fun gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-olu to sọ pe oun naa ti ṣe iṣẹ pulọmba ri ni bi ọgbọn ọdun sẹyin.

Gomina o deede si aṣọ loju ọrọ yii o, ọrọ ni n ba moko-moro wa.

Gomina Sanwo Olu sọ ọrọ yii níbi ayẹyẹ ikẹkọọ jade awọn akẹkọọ 6,252 to kọ iṣẹ ọwọ ni awọn ibudo ikọsẹ mejidinlogun to jẹ ti ijọba nipinlẹ naa.

Sanwo-olu gba awọn ọdọ ati awọn obinrin ni imọran, lati gbaju mọ isẹ ọwọ, dipo kii wọn o ma a reti pe iṣẹ yoo jade lati ọdọ ijọba tabi ileesẹ aladani.

Ko tan sibẹ o, Sanwo-olu rọ awọn akẹkọọ jade naa, lati lo anfaani isẹ ti wọn kọ, fi sọ ara wọn di ẹni to n gba eeyan si iṣẹ.

O tun rọ wọn lati tubọ ma a wa imọ kun imọ l'ẹnu isẹ wọn.

Awọn isẹ ọwọ bi i irun ṣiṣe, ṣíṣe ara loge, oúnjẹ sise, imọ kọmputa, irun gige, bàtà ṣíṣe, aṣọ rírán, ati awọn miran.

Kọmisanna fun ọrọ awọn obinrin ati fifi opin si óṣi nipinlẹ Eko, Cecilia Dada sọ pe iwe ẹri ti yoo fun awọn akẹkọọ naa ni anfaani lati wọ ileewe ijọba ipinlẹ naa, ti wọn ti n kọ isẹ ọwọ ni wọn yoo fun wọn.