Ekiti APC Politics: Mo mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ètè lásán lẹ̀ n sọ, ẹ ò lè yọ mí lẹ́gbẹ́ - Fayemi

Fayemi

Oríṣun àwòrán, Google

Bi aawọ ni ka pe e ni tabi ọrọ ija gidi, a o le sọ pato bo ṣe n lọ laarin ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ekiti.

Idi ni pe oniruuru igbesẹ to n waye lẹnu ọjọ mẹta yii ati gbọyi sọun laarin awọn eekan ẹgbẹ ko ye wa si.

Lakọkọ, lọjọ Ẹti la gbọ pe wọn ti ni ki gomina Ekiti, Kayode Fayemi lọ rọọkun nile.

Kia ti iroyin gbode pe awọn ọmọ ẹgbẹ kan yọ Gomina Kayode Fayemi lẹgbẹ ni akọwe agba rẹ, Ọgbẹni Yinka Oyebode ti fesi si iroyin yi.

O ni awọn ko ba ma sọrọ lori iroyin ofege yi ṣugbọn awọn ṣe bẹẹ nitori ki akọsilẹ ba a le wa lọjọ iwaju.

Oyebode ni awọn ti wọn yọ kuro lẹgbẹ lo ko ara wọn jọ lati kede pe awọn naa yọ Gomina Fayemi nipo.

Oríṣun àwòrán, Omotosho/Paul

Bi Oyebode ti ṣe n sọ tiẹ, bẹẹ naa ni arakunrin Omotosho Paul n darukọ Babafemi Ojudu ati awọn mii ninu atẹjade lati yọju sọ boya lootọ ni wọn ni awọn yọ Fayemi kuro lẹgbẹ.

Omotosho ni o jẹ alaga igbimọ tẹẹkoto ti apapọ ẹgbẹ APC lawọn mọ ni Ekiti.

Lati le fi ọrọ yi rinlẹ daada, Yakubu Nabena to jẹ igbakeji alukoro ẹgbẹ APC lapapọ naa n fi ọrọ sita loju opo Twiter

Nabena ni ki awọn ọmọ ẹgbẹ APC ni Ekiti ma ṣe mikan nitori awọn ko mọ si iyọni kuro lẹgbẹ Gomina Fayemi ati awọn mii to n ja rain.

Atẹjade rẹ sọ pe irọ gbaa ni igbesẹ naa tori pe ọfiisi ẹgbẹ ko tii gba ọrọ kankan latọdọ ẹka ti ipinlẹ Ekiti lori yiyọ Fayemi kuro lẹgbẹ.

O fi kun un pe wamuwamu lawọn wa ''pẹlu aṣẹ igbimọ amuṣẹya ti gomina Mai Mala Buni dari bi aarẹ Buhari ṣe rọ awọn, ki awọn ọmọ ẹgbẹ l'Ekiti si rọra ṣe".

Oríṣun àwòrán, Yemi0ke/Twitter

Ki nidi ti ọrọ "a yọ ọ́ lẹgbẹ fi kọkọ waye?

Iroyin to kọkọ jẹ jade lowurọ ọjọ Ẹti ni pe idi ti awọn kan fi lọ buwọlu iwe pe awọn yọ gomina Fayemi ni pe o ṣiṣẹ tako oludije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣẹlu APC, Pasito Ize Iyamu ninu idibo sipo gomina to lọ ni Edo.

Ṣaaju akoko yii, gbọnmi si i, omi o to o ti wa laarin ẹgbẹ oṣelu APC ni Ekiti ti ẹgbẹ naa ṣẹ pin si meji eyi ti awọn kan tẹle gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi, ti awọn miran si tẹle Sẹnetọ Ojudu.

Ṣugbọn atẹjade tuntun latọdọ ẹgbẹ ti ni ko sohun to jọ pe wọn yọ gomina Kayode Fayemi kuro lẹgbẹ APC.

Oríṣun àwòrán, Fayose/ Facebook

Ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí lé gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti, Kayode Fayemi kúrò ní APC

Aawọ to n lọ lẹgbẹ oṣelu APC tun ti gba ọna miran yọ pẹlu bi apa kan ẹgbẹ amuṣẹya ẹgbẹ APC nipinlẹ Ekiti ṣẹ ni ki gomina Kayode Fayemi lọ rọkun nile.

Ẹsun ti wọn fi kan Gomina Fayemi ni wi pe oun ṣiṣẹ tako ẹgbẹ oṣelu APC,eleyii to tako ofin ẹgbẹ.

Lara ẹsun ti wọn fi kan gomina Fayemi ni wi pe o ṣiṣẹ tako oludije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣẹlu APC, Pasito Ize Iyamu ninu idibo sipo gomina to lọ ni Edo.

Bakan naa ni awọn ẹgbẹ SEC ni APC ni ipinlẹ Ekiti naa sọ wi pe ki alaga ẹgbẹ naa, Paul Omotosho lọ rọkun nile ati awọn ajọ amuṣẹya miran.

Igbeṣẹ yii waye lai ti pe wakiti mẹrinlelogun ti ẹgbẹ oṣelu naa le oluranlọwọ pataki fun aarẹ Buhari, Senator Babafemi Ojudu ati awọn mẹwaa miran kuro ninu ẹgbẹ APC.

Ija laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ekiti ko ṣẹyin bi ẹgbẹ naa ṣẹ pin si meji ti awọn kan tẹle gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi, ti awọn miran si tẹle Sẹnetọ Ojudu.

Awọn onwoye eto idibo ni o ṣeeṣe ki ija naa niiṣe pẹlu eto idibo sipo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ naa ni ọdun 2022.

APC Ekiti pàṣẹ lọ rọ́ọ́kún nílẹ̀ fún àna Tinubu àti Babafemi Ojudu

O ti n sebi ẹni rugbo bọ ninu ẹgbẹ oselu All Progressives Congress ni Ipinlẹ Ekiti nibi ti wọn ti ni kawọn eekan ẹgbẹ kan lọ rọọkun nile.

Atẹjade kan to gbori ayelujara lati ri pe ẹgbẹ naa ti ni ki oludamọran aarẹ Buhari Sẹnẹtọ Babafemi Ojudu ati ana Asiwaju ẹgbẹ APC Bola Tinubu, iyẹn Oyetunde Ojo lọ rọọkun nile.

Yatọ si awọn wọnyi, awọn mẹsan mii ni ẹgbẹ sọ pe ki wọn lọ sinmi nile nitori pe wọn gbe igbesẹ to tako ẹgbẹ.

Oríṣun àwòrán, Femi Ojudu/Kayode Fayemi Facebook

Ade Ajayi to jẹ agbodegba ẹgbẹ sọ sinu atẹjade yii pe awọn gbe igbesẹ yi lẹyin ti igbimọ iwadii sọ pe lootọ ni wọn tapa si asọtẹlẹ ẹgbẹ pe ki wọn maa se tako ẹgbẹ nile ẹjọ.

Awọn mii ti ẹgbẹ ni ko lọ sinmi nile ni Chief Akin Akomolafe; Bamigboye Adegoroye; Olusoga Owoeye; Dele Afolabi; Toyin Oluwasola, Bunmi Ogunleye, Dr Wole Oluyede; Ayo Ajibade ati Femi Adeleye

Saaju asiko yi, fakinfa ti n waye laarin Gomina Kayode Fayemi ati Sẹnẹtọ Babafemi Ojudu.

Bi a ko ba gbagbe awọn mejeeji takurọsọ lori pipin nkan iranwọ fawọn arailu lasiko Covid 19.

Awọn onwoye oselu ipinlẹ Ekiti ni ohun to n sẹlẹ yi le se akoba fẹgbẹ APC bi wọn ko ba tete wa wọrọkọ fi sada yanju aawọ ojojumọ laarin awọn eekan ẹgbẹ ni ipinlẹ naa.