US vice presidential debate 2020: Pence, Harris gbéná w'ojú ara wọn lórí àjàkálẹ̀ Coronavirus

Awọn oludije igbakeji aarẹ Amẹrika

Ọrọ bi ijọba ààrẹ Trump ko ti ṣe koju Covid-19 to l'amerika lo ṣebi ẹni mu fa-kin-fa a wa laarin awọn oludije sipo igbakeji aarẹ ninu itakurọsọ to waye lọjọru.

Igbakeji aarẹ Trump iyẹn Mike Pence ati oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu Democrats Kamala Harris ni wọn jijọ kopa lori itakurọsọ naa lori ẹrọ amóhunmáwòrán.

Ninu itakurọsọ naa, Harris naka aleebu si ijọba Trump pe "aikoju ajakalẹ naa jẹ ikuna to buru ju ninu akọsilẹ isakoso ijoba ni Amẹrika".

Ọgbẹni Pence da a lohun pada pe niṣe ni Joe Biden n se adakọ ilana awọn to si n pe ni ojulowo ọna tirẹ lati koju Covid-19.

Ọgbẹni Biden lo n lewaju ninu "polls" bayi ti ìdìbo ku ọjọ mẹtadinlọgbọn.

Itakurọsọ awọn igbakeji ààrẹ yii dabi ẹni pe wọn fi ẹlẹ ṣe e ni afiwe eyi to waye kẹyin laarin Trump ati Biden lọsẹ to kọja.

Eeebu lo pọ ninu ọrọ ti itakurọsọ t'awọn oludije ipo aarẹ ọhun.

Ọgbẹni Pence ko da ọrọ mọ Kamala Harris lẹnu to bi aarẹ Trump ti ṣe ṣe fun Biden lasiko to n sọrọ.

Lẹnu igba meloo kan to da ọrọ mọ ọ lẹnu, Kamala Harris fi ẹlẹ sọ fun pe"Ọgbẹni igbakeji aarẹ, emi ni mo lanfaani lati sọrọ. Emi ni wọn ni ki n sọrọ"

Iṣẹlẹ kan waye t'awọn eeyan mẹnu ninu itakurọsọ naa ìyẹn nigba ti eṣinṣin kan ba lori igbakeji ààrẹ Pence to si duro sibẹ fun bi isẹju meji.

Amọ ṣa, itakurọsọ naa ṣi yi gbona diẹ.

Àkọlé fídíò,

Ondo Elections 2020: Ọgọ́rùn-ún ọdún tí a máa lò lórí oyè l'Ondo, ẹ ó rí àrà - Ojon YPP

Bawo ni Ọrọ Covid-19 ṣe mu ariyanjiyan wa?

Ninu itakurọsọ wakati kan aabọ yi to waye ni fasiti Utah, arabinrin Harris fẹsun kan ààrẹ Trump ati igbakeji rẹ pe wọn mọọmọ ṣi ara ilu lọna ni nipa ajakalẹ naa.

"Wọn mọ nipa arun yi ṣugbọn wọn f'ọwọ bo o mọlẹ fara ilu"

O fikun pe iwa ti wọn hu yi ti mu wọn padanu anfaani pe k'ara ilu dibo yan wọn lẹẹkan sii.

Ọgbẹni Pence sọko ọrọ si Biden ati Harris pada pe adakọ eto ati ilana ti ijọba awọn gbe kalẹ lati koju Covid-19 ni wọn n ji kọ pe t'awọn ni.

O fi ọrọ yi tabuku Biden nipa bo ti ṣe kuna nigba to dije aare lọdun 1987 nitori pe o ji ọrọ olori ẹgbẹ Labour ilẹ Gẹẹsi Neil Kinnock kọ lai gba iyọnda.