Male and Female Organ: Ìdí tí ọ̀rẹ́kùnrin tí mo ní fi kọ̀ mí sílẹ̀ torí mo jẹ obìnrin àti ọkùnrin

Obinrin to ni nkan ọmọkunrin ati ti obinrin

Bawo ni yoo ṣe ri lara yin tẹẹ ba taji loru tabi laarọ tẹẹ ṣẹṣẹ la ala ri ara yin pẹlu nkan ọmọkunrin ati ti ọmọbinrin papọ? Boya ẹ o sọ pe "Ọlọrun ma jẹ, mo ta ika rẹ danu".

Lawọn orilẹede to ti dagba eleyii loju aye gangan kii ṣe nkan aṣiri tabi yẹyẹ, amọ tori aṣa onikaluku yatọ ati ironu eeyan nipa nkan, iyatọ wa.

Akọroyin Khalifa Shehu Dokaji ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ajijagbara fun ẹda obinrin tawọn oloyinbo n pe ni Feminist to si fẹ pada di"obinrin tara rẹ pe lobinrin".

"Ati nkan ọmọkunrin ati tobinrin ni wọn bi mọ mi bo tilẹ jẹ pe nigba naa nkan ọmọkunrin naa n borii ti obinrin mọlẹ. Baba mi si mu mi lọ sile iwosan ṣugbọn tori iṣoro aile gbe bukata iwosan yii, wọn pa mi ti ko si nkankan ti wọn le ṣe si i".

Obinrin yii taa kan pe orukọ rẹ ni Tarusulu fi kun un pe bi oun ṣe n dagba si ni nkan ọmọkunrin oun n dagba to n tobi si i labẹ oun.

O ni: "mo ti pe ọmọ ọdun marunlelogun bayii ṣugbọn mi o ni iya mọ. ṣe ni nkan ọmọkunrin abẹ mi n tobi sii ṣugbọn oju ara mi gẹgẹ bi obinrin ni mo fi n tọ".

O fi kun un pe "bẹẹ ni mi o ki n ṣe nkan oṣu, mi o si ni ọmu laya bii ti obinrin".

Ẹni ọdun marunlelogun yii ni laalaa ti oun n la kọja tori eyi laarin awọn ọrẹ ati awọn ọmọ kilasi rẹ ko jẹ ko le maa darapọ mọ awọn eto ileeweni ko ba lọ ileewe mọ.

O sọ pe: Mo pade arakunrin kan to ti n ba mi sọrọ ifẹ ati igbeyawo ṣugbọn nigba ti wọn ta a lolobo pe kunrin ni mi, lo ba fẹsẹ fẹ ẹ. Mo tun ti ni ọkunrin mẹta bayii to fẹ fẹ mi ṣugbọn wọn o mọ pe obinrin ni mi".

O ni ṣugbọn ni toun, oun yoo jẹ ki wọn mọ ki nkan to waye tẹlẹ to tun ṣẹlẹ. Nibayii, mi o lọ si ileewe mọ tori idẹyẹsi.

Ni iha ariwa orilẹede Naijiria eyi tii ṣe ilẹ Hausa, awọn ọkunrin atawọn obi wọn lo maa n wa ni bebe idẹyẹsi ati ifilọkulọ lọni.

Mo ti fẹẹ pa ara mi, ọpẹlọpẹ eeyan to sare si mi

Koko afojusun Tarusulu ni lati yipada di obinrin ti ara rẹ pe ko baa le ṣegbeyawo bi gbogbo obinrin mii ṣe n ṣe ko di abiyamọ.

"Mo fẹ jẹ obinrin ki emi naa le ṣegbeyawo bii ti awọn ọrẹ mi. Ṣugbọn tori awọn obi mi o lagbara to, mo n bẹ ilu lati ran mi lọwọ. Tarusulu sọ bẹẹ.

Itan igbesi aye Tarusulu jẹ ọkan lara eyi to buru ju laarin awọn obinrin iha ariwa Naijiria.

Akọsilẹ fihan pe ọpọ obinrin lo ti n pa ileewe ti tori iwa ifipamuni.

Iha ariwa orilẹede Naijiria ti n fa sẹhin nipa ti imọ ẹkọ igbalode to si wa da bii pe ṣiṣe iwa ipa si yala akọ tabi abo laarin awọn akẹkọọ ẹgbẹ ara wọn lee jẹ okunfa ibẹru-bojo ni ẹkun naa.