Lagos gas explosion: Ènìyàn 5, ilé 25 ilé ìtajà 16 àti àwọn ǹkan mírà lo bá ìṣẹ̀lẹ̀ iná naa rìn.

Lagos gas explosion: Àjọ LASEMA ti pa iná to waye ni Ipaja

Oríṣun àwòrán, Alamy

Ìròyìn tó n tẹ́ BBC Yoruba lọ́wọ́ ni pé, àjọ LASEMA àti ilé isẹ́ panápana tí fòpin si jàmbá iná tó bẹ́ sílẹ̀ ní òwúrọ̀ òní ni agbègbè Ipaja ìpínlẹ̀ Eko.

Ọ̀gá àjọ náà Olufemi Oke-Osanyintolu sàlàyé pé àwọn ìjàmbá tó ṣẹlẹ̀ níbẹ tí òun sì le sàlàyé lọ́wọ́lọ́wọ́ okú ènìyàn mẹ́jọ ní àwọn ti rí báyìí.

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Osanyintolu sàlàyé pé, ilé igbé márùnlélógún, àwọn sọ́ọ̀bù mẹ́rìndinlógún àti ilké iwé alákọ̀bẹ̀rl kan wà lára àwọn dúkíà tó ti bá iṣẹ́lẹ̀ náà rìn lọ́wọ́lọ́wọ́

Àwọn ǹkan míran tó tún bàjẹ́ nibẹ̀ ni ilé alájà mẹ́rin tó fi mọ ilé itura kan, ọkọ tó n gbé afẹ́fẹ́ gáàsì, kẹ̀kẹ́ márúwá, ọkọ ẹru kan.

Ó fi kun pé, wọ́n ti ri ibi ti afẹ́fẹ́ gáásì ti n jáde wan si ti dii pa, sùgbọ́n ìwádìí àwọn ǹkan míran to báàjẹ́ níbẹ̀.

Bákan náà ni ọkọ mẹ́ta jóna nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Lagos gas explosion: Iná míì tún ti ṣẹ́yọ ní agbègbè Ipaja lówùrọ òní!

Oríṣun àwòrán, Lasema

Ajọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko LASEMA ní òun ti bẹ̀rẹ̀ ètò láti pa iná tó ṣẹyọ nilé epo kan ni Baruwa, àgbègbè ìpájà lówùrọ̀ òní.

Bákan náà ni fọ́nran kan jẹyọ lójú òpó twitter níbi ti àwn ará ìlú ti ń pe fún ìrànwọ́ láti pa iná náà.

Àkọlé fídíò,

Ondo Elections 2020: Ọgọ́rùn-ún ọdún tí a máa lò lórí oyè l'Ondo, ẹ ó rí àrà - Ojon YPP

Gẹ́gẹ́ bí ọgá àgbà LASEMA ṣe sọ, ìná náà bẹ̀rẹ̀ ni dédé ààgo mẹ́fa owúrọ ọjọbọ ọsẹ.

LASEMA ni "ati gbé ìgbésẹ̀, bákan náà ni a ó maa fi tó yín létí bi ó bá ṣe ń lọ".

Bakan naa, ileeṣẹ Ọlọpa ti fi ikede sita pe awọn ti ran ikọ amuṣẹya lọ si oriko iṣẹlẹ naa lọgan.

Àkọlé fídíò,

Àwọn kan ṣónú bí wọ́n bá di gómìnà, ẹ fún wa láyè láti wá parí iṣẹ́ táa bẹ̀rẹ̀ - Akeredolu