Sotitobire: Ọkọ mi kò mọ̀ Jegede PDP rí, kódà kò fa ẹnikẹ́ni kalẹ̀ dípò Akeredolu- Bisola ìyàwó Alfa Sotitobire

Sotitobire: Ọkọ mi kò mọ̀ Jegede PDP rí, kódà kò fa ẹnikẹ́ni kalẹ̀ dípò Akeredolu- Bisola ìyàwó Alfa Sotitobire

Lati igba ti wọn ti gbe Ọkọ mi ni ọlọpaa ko ti wa ọmọ mọ- Bisola aya Wolii Sotitobirẹ

Idajọ buruku ni wọn da fun ọkọ mi ni ariwo ti Arabinrin Bisola Alfa to jẹ iyawo Wolii sotitobire n pa bayii.

O ni aṣiri ikọkọ wa lori idajọ naa ti ko han si ọpọ eeyan.

Aya wolii ṣalaye lẹkunrẹrẹ fun BBC Yoruba lori ohun to ṣẹlẹ gangan ati igbesẹ ti ọkọ rẹ gbe.

Bisola alfa sọ bi Woli se sanwo ikede ni gbogbo radio kaakiri ipinlẹ Ondo lati fi ṣawari ọmọ to sọnu, iyẹn Kolawole Gold.

O sọ irinajo ọkọ rẹ ni ọgba DSS ati ohun ti oju wọn ri to fun BBC Yoruba.

Bisola Alfa ni irọ oriṣiriṣi ni wọn pa mọ ọkọ ohun ati pe wolii kii ṣe oloselu.

Nitori ki BBC Yoruba ma baa jẹ agbẹjọ ẹni kan da to jẹ agba oṣika ni wọn ṣe kan si aya Wolii naa ko sọ iha ti ẹbi wọn lori idajọ naa.

Ki Olorun ṣawari Kolawole Gold to sọnu ni adura BBC.