Baldness: Àwọn tí irun wọ́n ti gbá rìfáàsì sọ ìrírí wọn àti àǹfàní tí wọ́n ń jẹ

Baldness: Àwọn tí irun wọ́n ti gbá rìfáàsì sọ ìrírí wọn àti àǹfàní tí wọ́n ń jẹ

Ṣé lóòtọ́ ni pé orí olówó ni ti apárí?

"...Ìgbà míì, àwọn báábà ò kí ń béèrè pé ṣé ẹ fẹ́ gẹrun orí, irun àgbọ̀n nìkan la máa ń gẹ̀ nígbà tí kò sí ǹkankan lórí, kondoro ni".

Awọn apari gbàgbọ pé púpọ nínú awọn to ṣe agbejade awọn nkan gidi lagbaye, apari ni wọn.

Iṣẹ abẹ irun

Ọkan ninu wọn ṣe afiwe onimọ Sayẹnsi, Michael Farraday gẹgẹ bi eeyan nla to si jẹ apari.

"Bí Ọlọrun bá tiẹ fún mi ní irun àgbọn, máà dúpẹ, àwọn kan wa to jẹ pe kodoro bayii ni."

Ni ti dokita, o sọ oniruuru idi ti eeyan le fi pa lori yala kunrin tabi obinrin.

Dokita Tunde Adeife jẹ ko di mimọ pe o le niṣe pẹlu ajogunba idile nigba miran. "To ba ti wa ninu idile kan, to jẹ wipe tẹẹ́ ba ṣa ọkunrin mẹwaa ninu idile, eeyan marun a pari ninu wọn, ẹ o ti mọ pe ajogunba ni".

Ni ti obinrin, o ṣalaye pe bi irun ti wọn maa n ṣe ba ti le ju to si yọ lati ibi gbongbo rẹ, obirin naa ti di apari niyẹ ti ko si si ohun ti onimọ iṣegun oyinbo kankan le ṣe si i.

O ṣalaye pe to ba kan ge laarin ni, atunṣe ṣi wa.

Remilekun Fatolu bú sẹ́kún fún ohun tó ti pàdánù láyé torí ọyàn ńla rẹ̀.

Ẹwẹ, dokita Tunde ni awọn ounjẹ afunilẹjẹ kan wa to le jẹ ki irun hu daadaa.

"Awọn abẹrẹ wa taa le lo, ti a ba ti gun ibi isalẹ ibi ti irun ti n jade wn a si lẹ wọn mọ ibi tori ti n pa ti yoo si bọ si deede pada".

Koda o ni awọn obirin gan lee pada ni irun iwaju to ti fa l sipakọ pada nipa aramanda iṣẹ ọwọ awọn.