Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ipò Ọba

Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ipò Ọba

Oba Adedokun Omoniyi Abolarin Aroyinkeye 1, Orangun Oke Ila sọrọ ilẹ kun!

Òrí ló yan iṣẹ́ olùkọ́ fún mi ni ń kò ṣe jẹ́ kí Ọba ti mo jẹ́ dí mi lọ́wọ́- Kabiesi Abolarin Oke Ila

Kabiesi ṣalaye idi ti o fi da ileẹ̀kọ́ Abolarin silẹ ni Oke Ila fun awọn ọmọ alaini lawujọ.

O ni awọn akẹkọọ to ku diẹ kaato fun ni ile ẹ̀kọ́ naa wa fun.

Kini Kabiesi tun sọ fun BBC?

Kabiesi ni iṣẹ olukọ ni oun ti n ṣe ni eyi ti oun ko le yipada lẹyin ti o di Ọba ati pe pataki ipo Ọba ni lati mu ayipada rere ba awujọ ti eeyan n dari.

Awọn to ku diẹ kaa to fun ni aayo mi ni ọrọ Oba Abolarin.

Ati pe Kabiesi funrarẹ n kọ awọn ọmọ ni iṣẹ eto ijọba ti a n pe ni 'Government' ni eyi ti wọn si n ṣe daadaa.

Oba Adedokun Omoniyi ni ọja ọla Naijiria lo jẹ oun logun ati mimu ayipada

BBC Yoruba ba ninu awọn akẹkọọ ile iwe ọfẹ Kabiesi sọrọ nipa iriri wọn.

Kini awọn akẹkọọ ikeji Orisa sọ?

Adeola Stella Oluwafeyisola ati Tijani Yusuuf salaye bi awọn ṣe jẹ omo orukan ṣugbọn ti Kabiesi ti fun wọn ni ireti tuntun.

Kabiesi parọwa fun awọn eeyan pe ki onikaluku ṣe ohun to yẹ fun awọn alaini to wa nitosi rẹ.

O mẹnuba awọn akẹkoo ọmọ Abraka, ọmọ ebonyi, ọmọ Benue ati Plateau to jẹ anafani ẹkọ ọfẹ ni Oke Ila Orangun ni eyi to fihan pe ko yẹ ki a ni ẹlẹyamẹya.