Omolola Arohunmolase Welder: Mo ti fí iṣẹ́ 'Welder' gbayì láwùjọ, tó mo fi tọ́ ọmọ yanjú

Omolola Arohunmolase Welder: Mo ti fí iṣẹ́ 'Welder' gbayì láwùjọ, tó mo fi tọ́ ọmọ yanjú

Lati ile iwe girama ni mo ti n kọ iṣẹ- Iya Wẹda, Omolola Arohunmolaṣe.

Arabinrin Omooba Omolola Modupe Oluwa Arohunmọlaṣẹ jẹ obinrin ti ọpọ gba pe o n ṣiṣẹ ọkunrin.

Iya Welder bi ọpọ ṣe n pe Omolola Arohunmolase ṣalaye fun BBC Yoruba nipa irin ajo aye rẹ ko to di ogbontarigi ajorin-mọrin bayii.

Bẹẹ, ọmọ ti yoo jẹ aṣamu ti gbọdọ ṣe ẹnu ṣamuṣamu lati kekere, o ni o le ni ogun ọdun ti oun ti n ṣiṣẹ yii.

Koda, o mẹnuba irufẹ ifẹ ti oun ni lati maa ṣe iṣẹ to lagbara, to le to jẹ iṣẹ ti a mọ ọkunrin mọ ni eyi ti oun fi lọ ka sii nipamiṣẹ afi-irin-dara sii ni Institute of Technology.

Bakan naa ni Omolola sọ nipa ipenija rẹ lẹnu iṣẹ yii ni kikun.

Odunayo, ọmọ iya welder naa sọ pe gbogbo ẹbi lo fọwọ si iṣẹ iya rẹ yii ati pe ko sohun to buru nibẹ.

Ni ipari ni Omolola gba awọn obinrin ni imọran lori ohun to yẹ ni ṣiṣe.