DJ Kulet Kudirat Gbemisola yàn ijó jíjó àti fífi orin Fuji nìkan dá àwọn èèyàn nínú dùn lá
Kudirat Gbemisola lo pa orukọ da di DJ Kulet to n fi iṣẹ DJ dara, ara gidi lawujọ.
Lootọ ko jẹ tuntun mọ ki obinrin maa ṣe iṣẹ DJ amọ ti Kudi yatọ.
Kulet gẹgẹ bi inagijẹ rẹ, kan dede yan lati maa ṣa awọn orin Fuji atawọn to fara pẹ ẹ nikan safẹfẹ.
- Ṣé o mọ iye òṣèré fíìmù Yorùba àti olórin tó bá ọdún 2020 lọ?
- Àwọn àmi méje tó ń tọ́ka sí pé oò kí ń mu omi bí ó ti tó
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa #IGotSurvivalFund owó ìrànwọ̀
- Wo ohun tí Pasuma sọ nípa Opeyemi, ọmọ rẹ tó di ọmọ ogun orí omi l'Amẹrika
- Àṣírí tú! Afurasí márùn ún pa Memunat Ẹlẹ́ja àti ọlọ́kadà, wọ́n pín ẹran ara wọn sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ
Ko si ani ani, eyi ti mu ko da yatọ laarin awọn akẹgbẹ rẹ to ku toripe jijẹ akọṣẹmọ ninu iruwa ogiri wa orin lawọn toku maa n dapọ.
Ọdun 2018 ni Kudirat bẹrẹ, ṣaaju akoko yii, ijo lo ni oun maa n jo kiri inawo oni inawo koda bi wọn o pe e, yoo lọ tori ijo lati da inu ara rẹ dun.
"Baba mi o fọwọ sii, iya mi o fọwọ sii, awọn ọrẹ mi naa o fọwọ sii, gbogbo wọn ṣaa da mi nu".

O ni ọpọlọpọ igba lawọn onibara naa maa n kọkọ wo oun pe ṣe o lee ṣe iṣẹ ti wọn fẹ gbe fun un yii ti wọn a si gbe e fun ọkunrin tori wọn gbagbọ pe iṣẹ ọkunrin ni.
Amọ aye ọpẹ pada yọ ninu nkan ti Kudirat DJ Kulet yan laayo.