Ogun Police: Ọlọ́pàá Ogun rí ₦2m, oògùn olóró ₦10m àti ọ̀pọ̀ ohun ìjà olóró kó níbùba olóògùn olóró

Police

Oríṣun àwòrán, NPF

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ogun ti ri owo to le ni miliọnu meji abọ naira ati oogun oloro, ti iye rẹ to miliọnu mẹwaa naira lẹyin ti wọn kọlu awọn eeyan kan ti wọn fura si pe wọn n gbe oogun oloro.

Kọmiṣọna ọlọpa ipinlẹ naa, Edward Ajogun lo fi ọrọ naa lede nigba to n ṣafihan owo ati oogun ọhun, ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweran, nilu Abeokuta.

Ajogun sọ pe, awọn kọlu agbegbe ti awọn afurasi naa n farapamọ si nile itura Mayas to wa ladugbo Lafenwa, niluu Abeokuta, lẹyin ti awọn kan ta awọn lolobo.

O ni awọn ọlọpaa ri awọn owo ati oogun naa, ṣugbọn awọn afurasi ọhun na papa bora.

Oríṣun àwòrán, NPF

Kọmiṣọna ọlọpaa ṣalaye pe awọn afurasi naa ri aye sa asala nitori awọn fa ṣẹyin lati ṣina ibọn fun wọn, ki awọn ara ilu to wa lagbegbe ọhun ma ba a fara gbọta ibọn.

Lara awọn nnkan to ni wọn ri nibẹ ni owo ti iye rẹ jẹ din din ni miliọnu mẹta, ₦2,722,750, aadọfa idi igbo, 110, pali oogun codein aadọta ati pali poogun Rephnol mejila.

Àkọlé fídíò,

Ado Ekiti Blind Couple: Tọkọ-taya Oke ní Ọ́ba òkè ló fi àwọn dá àrà tó wù ú

Ko tan sibẹ, o ni wọn tun ri pali oogun Uniplex Codein, ti iye rẹ to miliọnu mẹwaa naira, pali Pandeen mẹrin, pali emzoline meji, atawọn ohun ija oloro bii aake, ada ati ogun abẹnu gọngọ.

Ajagun pari ọrọ rẹ pe, iṣẹ ti bẹrẹ lati ṣawari awọn afurasi naa, to na papa bora laipẹ.