Oyo Amotekun: Seyi Makinde fi ọkọ̀ ńla mẹ́rin dá ikọ̀ Amotẹkun lọ́lá nípìnlẹ̀ Oyo

Amotekun

Oríṣun àwòrán, Oyo Amotekun

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti ra ọkọ nla mẹrin fun awọn ikọ̀ Amọtẹkun ni ipinlẹ Oyo ki wọn ba le ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ.

Makinde ni awọn ọkọ yii ni ni wọn yoo ma a lo fun iwọde lati yika gbogbo ẹkun to wa ni agbegbe awọn.

Oríṣun àwòrán, Oyo Amotekun

Gẹgẹ bi ọrọ gomina, awọn ọkọ yii yoo jẹ ki o rọrun fun wọn lati pese aabo fun awọn eniyan, ki iwa ọdaran le diku ni agbegbe naa.

Makinde ni oun ko fi aye gba iwa ọdaran lọnakọna ni ipinlẹ naa, ki ilọsiwaju le de ba orilẹede naa.

Oríṣun àwòrán, Oyo Amotekun

Amọ, o kilọ fun ikọ Amọtẹkun lati jẹ apẹre eniyan rere nipinlẹ naa,nipa dida aabo bo ẹmi ati dukia awọn eniyan nipinlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Oyo Amotekun

Nigba ti o n fesi, adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Oyo, Ajagunfẹyinti Olayinka Olayanju gboriyin fun gomina Makinde fun atilẹyin wọn ni gbogbo igba.

Oríṣun àwòrán, Oyo Amotekun

Ọgagun Olayinka ni o da oun loju pe igbesẹ naa yoo fun awọn ikọ Amọtẹkun ni anfaani lati ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Oyo Amotekun