Akomolede ati Asa: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelowo Olufemi Lawrence

Akomolede ati Asa: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelowo Olufemi Lawrence

Wo diẹ lara abuda ara Ijapa gẹgẹ bii olu ẹda itan alọ apagbe Yoruba.

Iwe Alọ Ijapa apa Kinni ti Ọjọgbọn Adeboye Babalola kọ ni a n gbe yẹwo loni lori eto Akomolede ati Asa lori BBC Yoruba lonii.

Ogbeni Lawrence Olufemi Oyelowo lati ile ẹkọ CAC Grammar School ni Ọka, ni ipinlẹ Ondo ni guusu Iwo oorun Naijiria ni olukọ wa to dantọ fun tonii.

Kini idi ti Yoruba fi n lo ijapa gẹgẹ bii olu ẹda itan?

Kini laarinja ijapa fun ra rẹ?

Oríṣun àwòrán, others

Awọn abuda adamọ wo lo wa lara ijapa?

Kini idi ti irisi ijapa fi jẹ afiwe fun Yoruba?

Awọn ibeere yii ati omiran ni olukọ wa Oyelowo Olufemi dahun ninu idanilẹkọọ kilaasi toni lori eto Akomolede ati Asa lori ikanni BBC Yoruba.

Eto yii n waye pẹlu ajọṣepọ ẹgbẹ onimọ ede Yoruba, YSAN ati apapọ ẹgbẹ Akomolede ni Naijiria.

Ojú sánmọ̀ ní ẹ̀yìn ìjàpá, ilẹ̀ ní aya rẹ̀- Olùkọ́ Oyelowo

Agbọnmagbọntan, Agọmagọju ati awọn orukọ miran ni ijapa n jẹ ninu alọ apagbe Yoruba.

Olukọ Oyelowo wa mẹnuba awọn ọgbọn ẹwẹ ti ijapa ni to fi n daabo bo ara rẹ lọwọ ewu, ọmọde ati agba.

Bakan naa ni a yannana bi Yoruba ṣe n n pa alọ apagbe, awọn ipede to maa n jẹyọ ninu alọ apagbe, iṣẹ ti Yoruba n fi alọ apagbe ṣe.

E kọ ẹkọ nipa alọ ijapa nibi....