Ìtanijí lórí BBC Yorùbá, Oluwo Jogbodo: Odú Iwori Obara bá wa sọ̀rọ̀ lórí ìfaradà tó pọ̀

Ìtanijí lórí BBC Yorùbá, Oluwo Jogbodo: Odú Iwori Obara bá wa sọ̀rọ̀ lórí ìfaradà tó pọ̀

Oluwo Jogbodo- Eto Itaniji lori BBC Yoruba.

Oluwori ni ẹda itan to jẹ ọdọ ninu ẹsẹ Ifa yii ni nkan ṣẹlẹ si.

Oun ni Ifa lo lati fi parọwa kikun lori Ifarada gẹgẹ bii ọkan lara iwa omoluwabi ni ilẹ Yoruba.

Aini ati iṣẹ́ ati òṣì n ba Oluwori finra pupọ.

Lẹyin ọpọlọpọ ironu lo tọ Babalawo lọ lati lọ bi ilẹ leere.

Ifa ni ko jẹ oye Makanjuọla, ko dẹ tun rubọ pẹlu ifarada.

Wo bi Olodumare ṣe gba ọna ara yanju iṣoro ọdọ to ni ifarada ko to di ọlọla.

Oluwo jogbodo rọ awọn ọdọ asiko yii lati ni igbiyanju, ki wọn tẹpa mọṣẹ.

O ni ifarada lo ku lati ni ọjọ ọla to dara fun eni ti kii ṣe ọlẹ to.

Oríṣun àwòrán, others