Femi Fani Kayode ti kúrò nínú ẹgbẹ́ PDP wá sí APC - Yahaya Bello

Fani-Kayode ṣe ìpàdé pẹ̀lú ẹgbẹ́ APC, àwọn kan ní 'torí ìdìbò 2023 ni

Oríṣun àwòrán, yahaya Bello

Gomina ipinlẹ Kogi Yahay Bello ni minisita fọrọ irina oju ofurufu tẹlẹri Femi Fani-Kayode ti kuro ninu ẹgbẹ oselu People's Democratic Party (PDP) wa sinu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Party (APC).

Ninu fọran kan to safihan ayẹyẹ ẹtọ ẹgbẹ APC kan ni Kogi ti yahaya fi sita lọjọru, Bello ni kikuro ninu ẹgbẹ PDP jẹ ọkan lara aṣeyọri rẹ gẹgẹ bi olori igbimọ to n gbaruku ti ọdọ lasiko iforukọ silẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ.

Ninu ọrọ rẹ: " arakunrin wa, ọrẹ wa oloye Femi Fani Kayode ti darapọ mọ ẹgbẹ oselu wa pẹlu ọkan kan, o n darapọ mọ ẹgbẹ wa lati wa fi imọ ati iriri ran ẹgbẹ APC lọwọ."

Àkọlé fídíò,

Kété tí wọ́n bá ti báa yín sùn tàn torí pé ẹ tóbi, ẹ gbà pé ìfẹ́ yẹn ti parí - Auntie Remi Ọlọ́yàn ńlá

"Ẹ ranti pe oloye Femi Fani-Kayode jẹ ọkan lara awọn to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC lati ibẹrẹ pẹpẹ ni bayii o ti gba lati wa darapọ mọ wa, O bami sọrọ , a ti pe gẹgẹ bi iṣẹ ti a ran mi lati inu ẹgbẹ mi o gbọdọ dẹyẹ si ẹnikẹni.. gẹgẹ bi ọrọ Gomina.

Komisọna ibaraẹnisọrọ nipinlẹ Kogi Kingsley Fanwo ninu ifọrọwanilẹnu wọ pẹlu oniroyin ni Kogi sọ pé ọrọ ti wọn sọ pe gomina Yahaya Bello sọ yii ninu fọnran kan to n foka lori ayelujara pe, ootọ ni.

Sùgbọ́n lánàá òde òní ni Femi Fani-Kayode gbe sójú òpó twitter rẹ pé, òun kò ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Fani Kayode

Àsìkò yìí la gbúdọ̀ pa jíjẹ́ ọ̀ta ara ẹni tì lẹ fi rí mi ní ìpàdé pẹ̀lú APC - Femi Fani Kayode

Oríṣun àwòrán, Fe

Minisita fun irina ofurufu tẹlẹri, Femi Fani-Kayode ti ṣalaye idi ti awọn eeyan ṣe ri i pẹlu awọn mọ ẹgbẹ oṣelu APC kan ti wọn jọ n ṣepade.

Eyi ti n mu iriwisi ọtọọtọ jade lori ayelujara ti awọn ọmọ Naijiria n sọ ero wọn jade pe boya o ti dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa abi ko dara pọ mọ wọn.

Oriṣiriṣi iroyin lo ti n lọ pe awọn adari ẹgbẹ́ oṣelu All Progressives Congress, APC, ti n sepade pẹlu awọn gomina mẹrin lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP, ki wọn o le fi ẹgbẹ naa silẹ, nitori idibo ọdun 2023.

Iroyin sọ pe Minisita nigba kan fun irinajo oju ofurufu, Femi Fani-Kayode, ṣe ipade pẹlu Alaga fidihẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC, Mai Mala Buni, ati gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello.

Àkọlé fídíò,

Ṣé o mọ oríkì ìlú ara rẹ tó olùkọ́ yìí tó dántọ́ lẹ́nu rẹ̀ bíi ọmọ ìlú rẹ?

Bo tilẹ jẹ pe iroyin naa sọ pe ẹgbẹ APC ti ba Fani-Kayode sọrọ lati kuro ni PDP, ko si darapọ mọ wọn, Fani-Kayode ti sọ loju opo ayelujara Twitter rẹ pe ijiroro nipa idagbasoke, isọkan, ati ọjọ iwaju Naijiria ni awọn ṣe.

O ni "o ya oun lẹnu pe awọn eeyan kan mu ki ọrọ naa dabi pe ko bojumu ki oun joko pọ pẹlu awọn adari ni Naijiria lati jiroro lori awọn nkan to rọ mọ isọkan, ọjọ ọ̀la, ati iduro ṣinṣin orilẹ-ede wa".

Fani-Kayode ṣalaye pe ifọwọsowọpọ ni agbo oṣelu, ẹsin, ati ẹkùn gbogbo lo tọ́ lati le gba Naijiria la.

"Mi o ni fi igba kankan tabi nitori ohunkohun ya kuro ni oju ọna otitọ, ti mo fi n polongo pe a nilo lati ma ṣe ojú ṣáájú, ki idajọ o fẹṣẹ mulẹ, ki Naijiria le duro.

" Pe mo si n ṣe ipade pẹlu awọn olori, ti ko yọ awọn ọmọ ẹgbẹ to wa nipo silẹ, ko tumọ si pe ma a yi ọrọ ẹnu mi pada."