2021 Ebola Outbreak in Guinea: Ebola tún dé sílẹ̀ Adúláwọ̀, kí ní ṣíṣe?

Ebola

Oríṣun àwòrán, others

Kini ẹyin ranti nipa Ebola?

Ebola ni ajakalẹ arun ti o maa n mu iba, ara wiwo, ara riro ati ọna ọfun didun dani.

Nigba to ba ya, ẹni naa yoo bẹrẹ si ni bi, yoo maa yagbẹ, ti yoo si maa da ẹjẹ ninu ati lara.

Enikẹni to ba ni ibaṣepọ pẹlu ẹni to ba ti ni ebola naa yoo koo lara rẹ ni.

Ara ilaagun, omi ara, afẹfẹ ẹnu ati eemi imu, ẹjẹ, eebi, igbẹ, ati omi ni wọn ti n ko ajakalẹ Ebola.

Awọn alaisan rẹ maa n ku lati ara pe omi ara wọn tan ni tabi ki awon ẹya ara wọn kọ iṣẹ silẹ.

Ebola tún dé sílẹ̀ Adúláwọ̀, kí ní ṣíṣe?

Orilẹ-ede Guinea nilẹ Adulawo ti kede pe ajakalẹ arun Ebola tun ti bẹ silẹ lọdọ wọn.

Wọn ni eeyan mẹta lo ti gbẹmi mi lẹyin iṣẹlẹ yii ti awọn mẹrin miran si ti n bi, ti wọn n yagbẹ ọrin, ti ẹjẹ si n da lara wọn lẹyin ti wọn lọ sinku nọọsi kan nibẹ.

Awọn alaṣẹ ti kede pe awọn yoo ra abẹrẹ ajẹsara tuntun lati ọdọ ajọ eleto ilera ni agbaye (WHO) lati tete dẹkun itankalẹ Ebola.

Lọdun 2013 si ọdun 2016 ti ajakalẹ arun naa ṣọṣẹ pupọ ni orilẹ-ede Guinea ati Liberia ati Sierra Leone to sunmọ wọn.

Nibẹ si ni wọn ti gbiyanju lati gbogun ti ebola titi de orilẹ-ede Republic of Congo.

Oogun / abẹrẹ ajẹsara Ebola nibo ni iṣẹ de duro?

Ajọ WHO ni awọn ti wa ni sẹpẹ lati mojuto ọrọ ajakalẹ arun Ebola tuntun yii.

Wọn ni wọn ti n sọrọ papọ pẹlu ileeṣẹ to n pese abẹrẹ ajẹsara lati gbogun ti Ebola ki won le pese rẹ lọpọ yanturu.

Ileeṣẹ iroyin EFP ni Alfred Goerge Ki-Zerbo to jẹ aṣoju ajọ WHo ni orilẹ-ede Guinea so pe igbesẹ ti bẹrẹ lati gbogun ti itankalẹ arun naa.

Àkọlé fídíò,

Ebola Virus: ìdí tí Ebola fi ń tàn kálẹ̀

Bawo lo ṣe bẹ silẹ lẹẹkan sii ni Guinea?

Wọn ni Nọọsi kan to n ṣiṣẹ nileewosan Goueké to sunmọ agbegbe Nzérékoré ni guusu ila oorun rẹ lo ku lọjọ kejilelogun, oṣu kinni ọdun ti wọn si sin in lẹyin ọjọ kẹrin.

Eeyan 11,000 lo ti gbẹmi mi ni Iwo oorun ilẹ Adulawọ lori ajakalẹ arun Ebola to bẹrẹ ni Guinea.

Ara ẹni to ba ni ebola maa n ṣakoba fun ẹlomii ti ko tii ni.

Ọjọ meji si ọsẹ mẹta lo fi n duro lara eeyan.

Orilẹ-ede Guinea yii naa ni ajakalẹ arun Ebola ti bẹrẹ lọdun 2013 nilẹ Adulawọ.

Aarẹ ibẹ ni ijọba ti bẹrẹ igbesẹ lati rii pe ko tan lọ si awọn orilẹ-ede miran to sunmọ Guinea.

Ọkan awọn eeyan mii balẹ diẹ nitori igbagbọ wọn ninu abẹrẹ ajẹsara tuntun to jade naa

Àkọlé fídíò,

Ondo Fulani Herdsmen: Àgbe mẹ́ta ní àwọn Fulani darandaran tún pa Ọ̀wọ̀, Ondo