World Language Day: Yoruba, Igbo, Ikwere, Itsekiri, Ishan, Hausa sọ ìdí tí èdè tiwa n tiwa fi jẹ́ ìwúrí

World Language Day: Yoruba, Igbo, Ikwere, Itsekiri, Ishan, Hausa sọ ìdí tí èdè tiwa n tiwa fi jẹ́ ìwúrí

Ṣé gbogbo èdè Nàìjíríà tó ń jáde lẹ́nu àwọn wọ̀nyí wú ẹ lórí gidi?

Gbogbo ọjọ kọkanlelogun oṣu keji ni gbogbo orilẹede agbaye ya sọtọ gẹgẹ bi ayẹyẹ ayajọ ọjọ ede lagbaye.

Odegbami Omolabake to jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ ni ile ẹkọ imọ nipa aṣa ati iṣe Naijiria ti wọn n pe ni "Roots Academy" nibi ti wọn ti n ṣe ikọni gbogbo ede orilẹede Naijiria patapata lori ayelujara.

O sọ idi ti ayẹyẹ ayajọ ọjọ ede lagbaye ṣe jẹ nkan iwuri nipa gbigbe aṣa ati iṣe orilẹede Naijiria larugẹ.

Omolabake ni iṣẹ ti awọn n ṣe ṣe gẹgẹ pẹlu pataki ayẹyẹ ọjọ ede ni agbaye.

O fi kun un wipe nitori ayẹyẹ ayajọ ọjọ ede yii, anfani wa lati mọ nipa ede ẹya miran gan bi ẹnikẹni ba ni ifẹ si i.

Oludasilẹ eto ẹkọ naa lori ayelujara, Ben Nwokedi ni gbogbo ede ni awọn n kọ ti yoo si di mimọ laarin ọdun kan.