Bear attack Alaska woman: Bí ẹranko igbó ṣe bu ìdí obìnrin tó ń ṣe gáá lọ́wọ́ jẹ

Eranko Esi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Obinrin naa, Shannon Stevens ti fara pa to si figbe ta ninu irora bi ẹranko inu igbo kan, esi ti awọn oloyinbo n pe ni "bear" ṣe ya bo o to si bu u jẹ nidii.

Ninu igbo ti wọn n pe ni Chilkat Lake bush ni Shannon ti ni koun sare ṣe gaa afi fuu to fo soke o figbe ta foo lẹyin ti ẹranko esi naa bu idi rẹ jẹ.Ṣhannon Stevens ti farapa bayii lẹyin ikọlu ẹranko ọhun

Lẹyin to figbe bọ ẹnu ni aburo arabinrin naa ọkunrin sa jade pẹlu ina tọọṣi lọwọ lati lọ wa ori ẹranko naa latoju iho ṣalanga iyagbẹ.

Àkọlé fídíò,

'Ìgbẹ́ tí wọ́n ń yà síbí kìí jẹ kí oníbàárà wá sọ́dọ̀ wa'

Arabinrin ọhun sọ fun ile iṣẹ iroyin Associated Press pe lẹyin ti oun aburo oun ati ọrẹ oun ṣẹṣẹ din nkan ipanu sausage jẹ ta loun ni ki oun sare wọ ile igbọnsẹ afi ti ẹranko yii bu idi oun so.

Shannon n lo opin ọsẹ pẹlu aburo rẹ, Erik ati ọrẹ rẹ labẹ tampoli kan ni asiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Arabinrin Stevens ni o ṣeeṣe ki oju ọgbẹ naa jẹ boya ẹranko naa ge oun leyin jẹ ni tabi eekana.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Iru ile igbọnsẹ to maa n wa nita yii ni o ti ṣẹlẹ

"Kete bi mo ṣe fidi le ori nkan igbọnsẹ naa ni kini kan ge mi jẹ ni idi".

Àkọlé fídíò,

Ṣé o nífẹ̀ẹ́ láti kọ èdè ẹ̀yà Nàìjíríà míì ní kíákíá?

Wọn ti sare gbiyanju lati ṣe itọju akọkọ fun un eyi ti oloyinbo n pe ni "first aid".

Ẹka ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ẹranko igbo ni Alaska ni awọn ro o pe ẹranko yii to bu arabinrin Stevens jẹ lee jẹ esi dudu eyi ti ko si wọpọ laarin ẹranko.

Nibayii, arabinrin Stevens ni oun ti kọ ọgbọn, oun yoo si maa la oju oun daadaa bayii, farabalẹ wo inu ile igbọnsẹ ko to gbe idi le e lọjọ iwaju.

Àkọlé fídíò,

Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are