Arsenal vs Manchester City: Manchester City di àlejò ọ̀ràn sí Arsenal lọ́rùn ní Emirates

Arsenal vs Man City

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Manchester City di alejo ọran mọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lọwọ ni papa iṣere Emirates lẹyin ti City lu wọn mọlẹ bi aṣọ ofi ninu idije Premier League lọjọ Aiku.

Ko pẹ ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa ti Raheem Sterling gbayo sawọn Arsenal eyi to mu ki City lewaju ninu ere bọọlu ọhun.

Arsenal sọji nigba to ku diẹ ki ipele akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa pari, ṣugbọn gbogbo igbiyanju lati da ayo naa pada, pabo lo jasi.

Ipele keji ifẹsẹwọnsẹ ọhún naa gbona giri giri pẹlu bi Arsenal ti doju ija kọ City.

Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa de iṣeju marundinlọgọrin ni akọmọọgba Arsenal, Mikel Arteta yọ Pepe ati Odegaard, to si fi Alexandre Lacazette ati Smith Rowe rọpo wọn boya wọn le gbiyan lati ta biọbiọ, ṣugbọn lori ofo naa ni.

Pẹlun gbogbo igbiyanju Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, Manchester City papa ya aṣo iyi mọ wọn lara.

Lọwọ yii, Man City lo n leke tabili idije Premier League ọhun, nigba ti Arsenal wa lọwọ isalẹ ni ipo kẹwaa.

Àkọlé fídíò,

Lori iro: Ká ni àwọn Òbí mi gbà fún mí, èmi àti Sunny Ade á jọ máa 'Compete- Baba Lórí ir