Akomolede ati Asa Yoruba: Bí wọ́n bá fi màrìwò ọ̀pẹ lé ara ọkọ̀, ṣé o mọ̀ ìtúmọ̀ rẹ̀?

Akomolede ati Asa Yoruba: Bí wọ́n bá fi màrìwò ọ̀pẹ lé ara ọkọ̀, ṣé o mọ̀ ìtúmọ̀ rẹ̀?

Aroko pipa kii ṣe aṣa atọhun rin wa. Atayedaye lo ti jẹ aṣa ibilẹ Yoruba pataki ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin rara.

Olukọ wa toni, alagba Moses Ilupeju lori eto Akomolede ati Aṣa Yoruba gbayii pupọ pẹlu bo ṣe ṣalaye itumọ aroko lẹkunrẹrẹ.

Koda o mu iranti ọjọ pipẹ wa pe aroko a maa jẹ iṣẹ ti wọn ran an lai la ẹnu sọrọ rara.

Nipa Ogun jija abi bi ogun ba fẹ wọ ilu kan, oku sinsin, ijuwe ọna, ọrọ ifẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O fẹrẹẹ ma si iṣẹlẹ ti aroko ko lee ṣalaye nilẹ Yoruba.

Olukọ farabalẹ ṣalaye bi awọn ololufẹ meji ṣe maa n fi ọgbọn ba ara wọn sọ̀rọ laye atijọ.

To fi mọ ibọn yinyin, tita mariwo ọpẹ, lilo adiyẹ irana ati bẹẹ bẹẹ lọ lo ni itumọ.

Ṣe ẹ wa mọ pe aroko ni eewọ? "Laa han mi ni bata n ke", ẹ kọ ẹkọ latẹnu olukọ toni.