Tonto Dikeh: Ẹ wo ohun tí a mọ̀ nípa ìyànsípò Tonto Dikeh gẹgẹ bi aṣojú Àjọ tó ń rísí ìrínàjò àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi sí ilè ìlérí...

Tonto Dikeh

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oju opo ayalujara n gbona janjan lowuro oni ni lori arinyanjiyan nipa iyansipo gbajugbaja oṣere, Tonto Dikeh gẹgẹ bi aṣoju Ajọ to n risi irinna awọn ọmọlẹyin Kristi si ilẹ mimọ, Nigerian Christian Pilgrim commission, NCPC.

Tonto Dikeh ní Ọjọ Ẹti lo fi si oju opo Twitter rẹ ati Instagram wipe oun ti di aṣoju ọmọ lẹyin Kristi lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Dikeh loju opo ikansiraẹni naa lo fi ọpọlọpọ aworan to ya pẹlu adari ajọ irinajo ọmọlẹyin Kristi naa si ilẹ mimọ, Ẹniọwọ Yakubu Pam ninu ọfiisi rẹ ni ọjọ Ẹti naa.

Amọ, Ajọ irinajọ ọmọlẹyin Kristi ọhun ninu atẹjade ti wọn fi lede ni irọ patapata ni Tonto Dikeh pa lori iyansipo rẹ gẹgẹ bi asoju ''Ambassador'' ajọ naa.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ajọ NCPC ni igba akọkọ ti adari ajọ naa Pam yoo ri i ni igba ti o wa si ileeṣẹ naa ti wọn si gba a wọle lasiko abẹwọ rẹ.

''Tonto Dikeh wa polongo Ajọ rẹ, Tonto Dikeh foundation ni ati wipe wọn ṣetan lati fi ọwọ sowọpọ pẹlu ajọ naa lati pese iranwọ fun awọn eniyan to n lọ si okeere.''

O ni Tonto Dikeh ni ki awọn jọ ṣiṣẹ papọ lati mu alaafia wa si orilẹede Naijiria, nipa ajọṣepọ ajọ tirẹ ati ajọ irinna awọn ọmọlẹyin Kristi naa.

Bakan naa ni wọn sọ wi pe awọn ko buwọlu iwe adehun kankan pẹlu rẹ, ti ko si si atẹjade to fidi iyansipo naa mulẹ.

Ajọ naa wa rọ awọn ọmọlẹyin Kristi ati awọn ọmọ Naijiria lapapọ lati fi ọwọ osi da iroyin naa nu.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Amọ, Tonto Dikeh lasiko to n fesi si atẹjade awọn ọmọlẹyin Kristi naa ni Ajọ naa n pariwo nitori oun ni fidio to safihan iyansipo oun, amọ ko fi lede.

Tonto Dikeh fi kun un pe oun kii ṣe onirọ, amọ oun yoo kuro lori ọrọ naa ki alaafia le jọba.

Lori ayelujara, awọn ọmọ Naijria naa fi ohun wọn lede lori iṣẹlẹ naa, ti Mark Amaza si ni oun ko ri iṣẹ ti ajọ naa n ṣẹ ati wi pe kilo de to jẹ Tonto Dikeh ni wọn fi ṣe aṣoju wọn.

Gbajugbaja osere, Tonto Dikeh Dikeh da ajọ rẹ Tonto Dikeh Foundation silẹ ni ọdun 2000 lorilẹede Naijria.