Cities of illegal death: Wo àwọn ìlú tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni kí ènìyàn kú níbẹ̀

Itẹ oku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ta lo le ro o rara pe ki eeyan ku tun di ogun? Ṣe ogun laye ni?

Bẹẹni, ẹ o kuku ri baibai. Awọn ilu kan wa lagbaye to jẹ eewọ ni ki wọn ku ti ko si ba ofin mu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹ wo idi ti awọn ilu naa ṣe ti ara abuda yii jẹ abami:

Àkọlé fídíò,

'Mo kọ́kọ́ máa ń ro Amala mi fáwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́fẹ̀ẹ́ l'Amẹ́ríkà kí ojú mi tó ṣí tó ń já owó gidi fún mi báyìí'

1. Britiba Mitim - Brazil

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilu yii wa ni ipinlẹ Sao Paulo. Britiba Mirim ko ni ju aaye ilẹ isinku to ju fun eeyan ẹgbẹrun lọna aadọta (50,000) lọ. Eleyii ti di ki awọn oku maa fun mọ ara wọn ni iboji to si di ki wọn maa pin aye.

Olootu ilẹ naa ni gbe igbesẹ pataki lati ṣe ipẹjọ itagbangba lọdun 2005 pe ki ofin ti i lẹyin pe ẹṣẹ ni lati ku. Nitori eyi, bi eyan kan ba ku, wọn a ni ki awọn ẹbi wọn san faini tabi ki wọn lọ ẹwọn iye ọjọ melo kan gẹgẹ ijiya ẹṣẹ wọn ki wọn baa le tun wa aye ti wọn le gbẹ gẹgẹ bi iboji isinku si.

2. Itsukushima - Japan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilu Itsukushima tabi Miyajima jẹ ilẹ ini ẹka ajọ isọkan agbaye UNESCO ni orilẹede Japan eyi ti wọn tun mọ si "Shrine Island". Wọn fun erekusu naa ni orukọ yii tori wipe wọn ri i gẹgẹ bii ọlọrun mimọ funrarẹ to si jẹ ile fun ọpọlọpọ ojubọ ati pẹpẹ adura. Torinaa lati ri i pe ibẹ jẹ mimọ tori wọn ti fi ji fun awọn oriṣa, wọn ko faaye gba iku tabi bibimọ lori il erekusu naa lati dun 1978. Koda ko si ile iwosan tabi iboji ti wọn kọ sibẹ rara.

Àkọlé fídíò,

Jimi Solanke: Bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ eré òṣùpá láyé àtijọ́ táa mú ìtàn Yorùbá sísọ dé America padà

3. Lanjarón - Spain

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ldun 1999, Olootu ilẹ Lanjaron fi ofin de iku kiku niwọn igba to di pe awọn ibi itẹ oku ti ibil ti kun ti ẹmi awọn to ku ko si ni ribi sinmi lalafia. Ilu naa wa ni agbegbe Granada Province.

Lara ọna ti wọn gba gbe igbesẹ yii kọkọ dabi awada o si tun fara pẹ igbesẹ oṣelu lati fa oju awọn eeyan mọra si ọrọ naa. Nigba to si ti jẹ pe ofin naa di ootọ, wọn gba awọn eeyan ẹgbẹrun mẹrin niluu naa nimọran lati dakun wa ni ilera pipe titi di igba ti wọn yoo kọ ibi it oku tuntun.

Àkọlé fídíò,

Olaiya Igwe ló wá ra epo níbi tí mo ti ń di "nussle" epo mú mo bá bẹ́ mọ́ ọ́, bí ayé mi ṣe yí padà di òṣèré fíìmù rèé

4. Le Lavandou - France

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O jẹ ilu kan ni ẹkun Provence-Alpes-Côte d'Azur. Ilu yii gbajumọ fun ọpọ okun to wa nibẹ ati iwoye to dara o si ti di ibomiran to ti kun dẹnu.

Wọn ṣe ofin nibi lọdun 2000 eyi to lodi si ki awọn eeyan maa ku ni ilu Le Lavandou.

Àkọlé fídíò,

Gbogbo àwọn Barrister, Kolington tó jẹ́ kòríkòsùn Ayinla Ọmowura, kò sí èyí táa rí nínú wọn' - Haruna, ọmọ Ayinla

5. Longyearbyen - Norway

Oríṣun àwòrán, Getty Images

5. Longyearbyen jẹ ilu kekere kan ni Norway ti wọn mọ gidi gan fun iṣẹ wiwa eedu. Nibi yii, oju ọjọ maa n tutu gan ti yoo debi pe o di gan ti ko si ni jẹ ki ara awọn oku naa maa bajẹ eyi ti o lee fa itankalẹ arun si ara awn eeayan alaye. Nitorinaa gẹg bi ofin, o lodi si ofin ki eeyan ku ki wọn si sin in si Longyearben. Bo ba wa jẹ pe awọn kan ti sunmọ bebe iku, wọn a gbe ẹni naa lọ si "Mainland atawọn apa ibomii ni Norway nibi ti ko ti si iru ofin bayii.

Àkọlé fídíò,

Seye Malaolu: Bí mo ṣe rí àgbára ẹ̀jẹ̀ tó kúnlẹ̀, mò ń bèrè pé ṣé wọ́n pa Turkey níbí ni,

6. Sarpourenx - France

Oríṣun àwòrán, Tobias Titz

Lọdun 2018, olootu kan pa aṣẹ ranṣẹ si Sarpourenx pe o di eewọ fun awọn araalu lati ja fun ẹtọ wọn lati ku ayafi to ba jẹ pe wọn ti baba ni ojuko kan fun isinku laarin iboji to ti kun tẹlẹ.

Awọn alaṣẹ ti ṣe agbejade oriṣiriṣi ijiya fun awọn arufin. Igbesẹ yii tun pada bi ifẹhonuhan lati iha ti olootu gẹgẹ bi adajọ ṣe paṣẹ lodi si gbigbẹsẹ le ilẹ oko awọn eeyan fun anfani jijẹ ki ibi it oku fẹ sii.

7. Sellia - Italy

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Sellia jẹ ilu kan ni ẹkun Calabria ni iha Guusu orilẹede Italy nibi ti ida marunlelọgọta iye awọn araalu naa ti wọn o ju ọọdunrun le ọgọta to n gbe nibẹ lọ to le ni ẹni ọdun marundinlaadọrin.

Aṣẹ kan jade pe wọn fi ofin de awọn olugbe ilu naa pe ki wọn ma tilẹ ṣe aisan rara ka ma darukọ iku. Eyi wa fun lati le daabo bo adinku iye eeyan to wa nibẹ.

Ẹkunrẹrẹ aṣẹ naa paṣẹ pe awọn to ti n darugbo gbudọ kọ lati ku bo tilẹ jẹ wipe o jẹ ọna to lagbara lati maa mu awọn eeyan ni dandan lori ofin yii ki awọn eeyan le maa wa ni ilera pipe.

O fẹ da bii wipe ọna yii nikan ni olootu ijọba ilẹ naa le gba lati mu ki awn araalu wa ni ilere pipe.

Awọn iroyin yii jẹ otitọ amọ iṣẹlẹ abami gidi niwọn!