Plane crash in Abuja: Àwọn kan sọ pé ejò lọ́wọ́ nínú lórí ìjàmbá ọkọ̀ bàálù náà - Alàgbà Julius Olasunkanmi

Olasunkanmi

Alagba Julius Olasunkanmi to jẹ baba to bi Flight Sergent Olasunkanmi Olawunmi, to di oloogbge pẹlu awọn mẹfa miran ninu ijamba ọkọ ofurufu to ja lulẹ niluu Abuja ti sọrọ lori irufẹ iku to pa ọmọ rẹ.

Pẹlu ibanujẹ ọkan ni ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin ọhun fi ba awọn akọroyin sọrọ nipinlẹ Ekiti.

Ọkọ̀ bàálù tó mú ẹ̀mí ọmọ lọ l'Abuja ti lo ọdún 49 láyé - Bàbá Flight Sergent Olasunkanmi

Nigba to n sọrọ lori ohun to ṣokunfa iku ọmọ naa, o ni o pin si ọna meji, lakọkọ gẹgẹ bii ọmọlẹyin Kristi, o ni o ṣeeṣe ko jẹ amuwa Ọlọrun ni.

Lọna keji ẹwẹ, o ni o ṣeeṣẹ ko jẹ pe ejo lọwọ ninu lori ijamba ọkọ ofurufu naa to waye lọjọ Aiku.

Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin abẹle kan sọrọ, alagba naa ṣalaye pe "a tun le woo lọna miran, paapaa bo ṣe jẹ pe ọkọ baalu ọhun ti lo ọdun mọkandinlaadọta laye, ti iṣẹ rẹ ko si pe mọ."

"Koda, awọn kan tilẹ n sọ pe ejo lọwọ ninu lori ijamba naa, ṣugbọn ohun gbogbo to pamọ loju eniyan, kedere ni niwaju Ọlọrun."

Àkọlé fídíò,

Ọkọ mi bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lágo kan kó tó wọ bàálù tó já, àmọ háà! - Ìyàwó Olasunkanmi Olawunmi

Alagba Julius Olasunkanmi sọ pe o ba oun ninu jẹ pe iku mu ọmọ naa lọ ko to ri aye ṣe awọn nnkan to ti ṣeleri fun onu ṣaaju ki ọlọjọ to de.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ti ṣeleri pe oun yoo tun ile baba naa ṣe ko to di asiko ọdun Ajinde.

Bakan naa lo sọ pe o ti ṣeleri pe oun yoo lọwọ si iṣẹ atunṣe ile ijọsin wọn gẹgẹ bii onigbagbọ ti kii fi ọrọ ẹsin ṣere.

Alagba ọhun pari ọrọ rẹ pẹlu ẹbẹ pe ki ijọba ran ẹbi naa lọwọ, paapaa iyawo atawọn ọmọ ọkunrin mẹta to fi silẹ saye lọ.

Àkọlé fídíò,

Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ìròyìn Kayeefi akọnilẹ́nu hààà ṣẹlẹ̀ ní Ibarapa méjèèjè nígbà ìkọlù Fulani?