Signs of covid-19: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó ń ṣe ayédèrú abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ní South Africa àti China

Vaccine

Oríṣun àwòrán, @NVICLoeDown

Ileeṣẹ ọlọpaa South Africa ati China ti gbẹsẹle ẹgbẹgbẹrun ayederu abẹrẹ ajẹsara Covid-19, bẹẹ ni wọn tun fi panpẹ ofin mu awọn afurasi kan.

Ni China, awọn ọlọpaa fi ṣikun ofin mu ọgọrin eeyan nileeṣẹ kan ti wọn ti n po ayederu abẹrẹ naa, bẹẹ ni wọn si tun gbẹsẹle ẹgbẹrun mẹta abẹrẹ ajẹsara ọhun.

Ni South Afrca, awọn ọlọpaa mu ọmọ ilẹ China mẹta ati ọmọ orilẹ-ede Zimbia kan, wọn si tun gbẹsẹle ẹgbẹrun meji ati irinwo ayederu abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni Gauteng.

Ninu atẹjade kan ti ileesẹ ọlọpaa agbaye, Interpol, fi lede, wọn ni awọn ti gbọ iroyin nipa awọn ayederu abẹrẹ Covid-19 miran kaakiri awọn orilẹ-ede kan.

Interpol sọ pe awọn eeyan to n ṣe ayederu abẹrẹ naa ko tii bẹrẹ si n ta wọn lori ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin naa ni wọn sọ pe ayederu ni eyikeyi abẹrẹ ajẹsara ti eeyan ba ri ti wọn n ta, tabi polongo rẹ lori ayelujara.

Àkọlé fídíò,

Fulani-Yoruba Crisis: Oba Soun ló fí mi jẹ ọba Sabo ni Ogbomọṣọ- Alh Haruna Bala Abdulsala

Interpol ni ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe iwadii iwa ọdaran kaakiri agbaye, ilu Lyon, lorilẹ-ede France si ni olu ileeṣẹ naa wa.

Ẹwẹ, ko din ni miliọnu meji abọ eeyan ti Coronavirus ti mu ẹmi wọn lọ kaakiri agbaye.

Iye eeyan to si ti lugbadi arun naa ti fẹẹ to miliọnu marundinlọgọfa, gẹgẹ bii iwadii ti fasiti John Hpkins fi lede.

Àkọlé fídíò,

#EndSars Ogbomoso: Èmí kò ní kí wọ́n pa ọlọ́pàá tó pa Isisaka, ṣùgbọ́n...- Ramota, Iya Isi