Sunday Igboho latest: Sunday Igboho kò gba 'Award' ti a fún un ní Ogo Yorùbá nítorí inú rẹ̀ kò dún sóhun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ìran Yorùbá

Sunday Igboho latest: Sunday Igboho kò gba 'Award' ti a fún un ní Ogo Yorùbá nítorí inú rẹ̀ kò dún sóhun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ìran Yorùbá

To ba buru ju, Wale máa bọ ni Ibadan- Sunday Igboho ati awọn eeyan rẹ

Ogbeni Wale Adeoba ti ọpọ mọ si Mr Packaging ti kan si BBC Yoruba.

O ke gbajare sita pé oun n gba awọn ipe oriṣirisi to n dẹru ba ni lasiko yii lẹyin igba ti oun ti ṣe oludari eto Ogo Yoruba ti oun ṣe gbẹyin.

O fidi ẹ mulẹ pe Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho gan an ti ọrọ kan ko wa gba ami ẹyẹ ọmọ Yoruba to n ṣe daadaa ti Ogo Yoruba fẹ fun un.

O ni lati igba ti oun ti ṣeto naa tan ni orisiirisii wahala ti n ṣẹlẹ si oun bii ki awọn kan ti oun ko mọ ri deedee wa oun wa si ile.

Wale Adeoba to jẹ agbatẹru eto ifami ẹyẹ dani lọla Ogo Yoruba ni Ibadan ni awọn miran a pe oun ni ipe ijaya ti ẹru si n ba oun ki nkankan ma lọ ṣẹlẹ si oun laida.

O ni Koda, Oloye Sunday Igboho ko gba ami ẹyẹ naa nitori pe inu rẹ ko dun si ohun to n ṣẹlẹ si iran Yoruba lasiko yii ṣugbọn o wa sibi eto naa lati yẹ iran Yoruba si ni.

Bakan naa ni Wale Adeoba salaye pe Sunday Igboho ko lo eto naa lati fi ba ẹnikeni jẹ tabi tabuku oloselu kankan.

O salaye idi ti wọn ṣe gbe eto Ogo Yoruba Award ka lẹ fun idagbasoke iran Yoruba ati igbelarugẹ ede ati aṣa Yoruba ni.

Bẹẹ, Sunday Igboho ti ni to ba buruju ki oun maa bọ ni Ibadan ati pe oun ko tii fi to awọn agbofinro leti nigba ti BBC beere pe ki lo de, o ni ẹru n ba oun ni.

Wale Adeoba, Mr Packaging sọ ohun to ṣẹlẹ gangan nibi eto naa ati abajade rẹ bayii.

E gbọ ohun to sọ funra rẹ ninu fọnran oke yii.