Seyi Makinde: Wo ìlànà tí ìpínlẹ̀ Oyo yóò gbà fi pín abẹ́rẹ́ àjẹ́sára Covid-19 tó gbà

Seyi MAkinde, Gomina ipinlẹ Ọyọ

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde

Kọmisanna eto ilera nipinlẹ Oyo, Dokita Bashir Bello ti sọ pe awọn oṣiṣẹ eto ilera ipinlẹ naa ti wa si ipinlẹ Eko, lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ti wọn.

Nigba to n ba BBC sọrọ, Dokita Bello sọ pe ajọ to n mojuto eto ilera alabọde ni yoo mojuto lilo rẹ.

Ati pe idanilẹkọ yoo bẹrẹ lonii fun awọn eeyan tuntun ti yoo fun awọn eniyan ni abẹrẹ ajẹsara naa, nitori pe o yatọ si awọn abẹrẹ ajẹsara to ku.

O ṣalaye pe awọn eleto ilera ni yoo kọkọ gba a , lẹyin naa ni yoo kan awọn olori ilu, lẹyin naa ni yoo kan awọn ti ọjọ ori wọn ti le ni ọgọta ọdun.

O ni ipele ti yoo tun tẹle wọn ni awọn to wa ninu ewu.

Ọsẹ to kọja ni abẹrẹ ajẹsara ti AstraZeneca de si orilẹ-ede Naijiria.

Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo si ti gba lara rẹ ni opin ọsẹ to kọja.

Àkọlé fídíò,

Wo obìnrin kanṣoso láàrin àwọ́n ọkunrin agunẹṣin gbafẹ́ nílùú Ilorin àmọ́ tọ́kàn rẹ̀ yii