AstraZeneca vaccine side effects: Wo ìhùwàsí àwọn tó ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19

Awọn to n gba abẹrẹ ajẹsara

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ṣé àwọn èèyàn ń rẹ́rìín músẹ́ ni àbí wọ́n fa irun ojú pọ̀ mọ́ tì'pàkọ́?

Ti wọn ba ni ki wọn lọ pe bi tii ri wa, oun gaan lẹ ti riun to difa fun oriṣiriṣi ihuwasi apanilẹrin tabi amuni bere ibere to n ti oju awọn ti ti gba abẹrẹ ajẹsara Astrazeneca jade.

Lara iru ihuwasi awọn kọọkan to ti gba abẹrẹ ajẹsara Astrazenecca ti ijọba Naijiria n rọ gbogbo eeyan lati gba ree.

Oríṣun àwòrán, Presidency

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo lo kọkọ ṣide gbigba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni Naijiria.

Eyi waye lẹyin ọjọ kan ti wọn bẹrẹ si ni fun awọn oṣiṣẹ eto ilera ni Naijiria ni abẹrẹ naa.

Ile ijọba Aso Rock nilu Abuja ni aarẹ ati igbakeji rẹ ti gba ti wọn, wọn si ṣafihan eto naa lori amohunmaworan.

Oríṣun àwòrán, NPHCDA

Aarẹ Buhari sọ pe bi oun ṣe gba abala akọkọ abẹrẹ naa, oun rọ awọn ọmọ Naijiria to ni ẹtọ lati gba, ki awọn naa ṣe bẹ ẹ.

Àkọlé fídíò,

'Èmi àti ìyàwó mi ti ń gbé pọ̀ nínú ìgbéyàwó wa fún 60 years', ẹ wá kọ́ ẹ̀kọ́ lẹ́nu àgbà méjì

Lasiko yii ni awọn kan ni Naijiria n pariwo pe awọn o nifẹ si lati gba abẹrẹ ajẹsara Astrazeneca ti wọn gbe wa. Amọ agbẹnusọ aar, Garba Shehu ni ki awọn Naijiria ma ro ohun ti wọn n ro.

O ni lẹyin ti aarẹ gba tirẹ si apa tan, ara rẹ wa bo ṣe wa tẹlẹ to si tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ. O ni bi ipalara kankan ba pada wa, awọn ko ni fi ohunkohun bo "ṣugbọn titi di asiko yii, ko si ipalara kankan yala o lagbara ni abi o kere lori aarẹ. O n ṣe ohun to yẹ ko ṣe".

Oríṣun àwòrán, NPHCDA

Ọlọpaa kan ree ni ipinlẹ Oyo to n di oju mọ agbari torii pe o n gba abẹrẹ Astrazeneca.

Ẹlomiran ko tilẹ tii gba a amọ bo ṣe woye ihuwasi ẹni to ri to n gba a lọwọ ti fun un lesi lọkan ara rẹ boya oun naa yoo gba a tabi ko ni gba a.

Oríṣun àwòrán, NPHCDA

Ta lẹni a gba leti ta leti n ro ni ọrọ to wa ninu aworan eleyii. Ọtọ lẹni to n gba abẹ́rẹ́, ọtọ lni to n ba a tara.

Bẹẹ ba wo aworan yii daadaa, ọlọpaa to n gba abẹrẹ gan n rẹrin to si n gba a tọyaya tọyaya amọ akẹgbẹ rẹ kan lo wa lẹyin to n ba a kaanu gidi gan.

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lasiko ti Kọmisọna eto irina ni ipinlẹ Niger n gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 yii, gbogbo eniyan to wa nibẹ lo fẹrẹẹ di i mu tan pẹlu bo ṣe n tara to si di oju mọ agbari eyi to fihan pe o n dun un.

Ẹlomiran a tilẹ fẹẹ fere ge tori pe o fẹ ṣe ayẹwo tabi gba abẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, NPHCDA

Minisita eto ilera, Ọjọgbọn Isaac Ajewole ree to wa lara isọri kinni awọn to kọkọ gba abẹrẹ ajẹsara Astrazeneca bo ṣe gunlẹ si orilẹede Naijiria.

Iwoye oju rẹ yii fẹ jọ bi ni fi ọkan igbagbọ gbadura bi abẹrẹ naa ṣe n wọle si i lara.

Oríṣun àwòrán, CRSPHCDA

Ni agbegbe Itigidi, ijọba ibilẹ Abi ni ilu PortHarcourt ni Mama ẹni ọdun mejilelaadọrin yii ti lọ fi idunu gba abẹrẹ ajsara to si ni "inu mi dun pe abẹrẹ yii ti de si orilẹede Naijiria, awọn eeyan wa ko ni ku mọ".

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Amoṣa, ṣe abẹrẹ tilẹ wa lagbara tabi dun eeyan to irinṣẹ ti wọn fi n ṣe ayẹwo Covid-19?

Ahmed arakunrin ọmọ Yoruba to ti ko gbogbo mọlẹbi rẹ lọ fun ayẹwo Covid-19 ri sọ iriri rẹ fun BBC Yoruba.

Oríṣun àwòrán, OTHERS

"Ka ma parọ, kii ṣe iriri to rọrun rara lati lọ ṣe ayẹwo Covid-19 pẹlu iho imu ti wọn maa n ki irinṣẹ naa bọ. Ẹni ti ko ba le moju kuro ko lee gbe ara duro ki wọn ki nkan bọ ọ nimu".

Oríṣun àwòrán, NPHCDA

Lara awọn aṣaaju nilu naa kan ree lẹyin ti gomina rẹ ti gba. Boya o ti ro pe ko le du eeyan ni amọ nkan to ba nibẹ kọja pe ko le du eeyan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọrọ yii ko yọ orileẹede Naijiria nikan silẹ tori pe Yoruba bọ wọn ni ibi gbogbo ni wọn ti n da ina alẹ.

Eyi lo difa fun arabinrin ara ilẹ India yii naa to kan sẹkun ti oṣiṣ ilera kan si nilo lati wa mọ ọ taanu taanu bi ekeji rẹ ṣe n gun un labẹrẹ.