Hajj 2021: Ìjọba Saudi Arabia ti gbé àwọn ìlànà tuntun jáde fún àwọn tó fẹ́ ẹ́ ṣe Hajj

Awọn arinrinajo Hajj

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba orilẹ-ede Saudi Arabia ti kede pe dandan ni fun gbogbo ẹni to ba fẹ ṣe Hajj ọdun 2021, lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.

Ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede naa sọ pe ẹni naa gbọdọ ti gba abẹrẹ naa lẹẹmeji.

Ileeṣẹ iroyin kan ni orilẹ-ede naa, Saudi Gazette sọ pe ileeṣẹ eto ilera ni gbogbo awọn to ba fẹ ẹ wa fun Hajj gbọdọ gba abala keji abẹrẹ ajẹsara ti ajọ WHO fi ontẹ lu, ni ọsẹ kan ṣaaju ki wọn o to de Saudi Arabia.

Bakan naa ni arinrinajo gbọdọ mu esi ayẹwo aarun to ṣe ni ọjọ mẹta ṣaaju ko to o de orilẹ-ede naa dani.

Ko tan sibẹ o, awọn arinrinajo Hajj shun gbọdọ tun fi ara wọn si igbele fun ọjọ mẹta ti wọn ba de Saudi Arabia.

O si di igba ti ayẹwo ba fi han pe wọn ko ni aarun naa lara, ki wọn o to le jade fun iṣẹ isin Hajj.

Yatọ si awọn ilana yii, ileeṣẹ eto ilera tun fi dandan le pe awọn ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mejidinlogun si ọgọta ọdun nikan ni yoo ni anfaani lati kopa ni Hajj ọdun yii.

Awọn ilana to ku ni:

Dandan ni wiwọ ibomu

Bẹẹ si ni gbogbo olujọsin gbọdọ fi alafo mita kan ataabọ silẹ laarin awa wọn.

Ọgọrun eeyan pere ni anfaani wa fun lati jọin papọ lasiko kan naa

Fun awọn to n gbe ni orilẹ-ede Saudi, igbagbọ ileeṣẹ eto ilera ni pe ìdá ọgọta awọn to n gbe ni Mecca ati Medina ni yoo ti gba abẹrẹ ajẹsara ṣaaju asiko Hajj.

Ilana gbigba abẹrẹ ajẹsara ẹẹmeji naa ko yọ wọn silẹ

Itankalẹ aarun Covid-19 ko jẹ ki eto Hajj waye lọdun 2020, bo ṣe yẹ ko ri. Ẹgbẹrun kan eeyan lo lanfaani lati kopa.