Akeredolu: Gómìnà Ondo fẹ́ kí ìjọba wà nkán ṣe ní kíá lórí ààbò Nàìjíríà bí bẹ́ẹ̀ kọ́

Oríṣun àwòrán, Google
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti gbe lẹyin akẹgbẹ rẹ Gomina Samuel Ortom ipinlẹ Benue lori ọrọ ipenija aabo to n ba Naijiria finra.
Akeredolu bii ti Ortom, ni ipenija aabo to n koju Naijiria le kọdi idibo ọdun 2023 ti ijọba ko ba wa wọrọkọ fi ṣada.
O ṣalaye ọrọ yi nigba to n kopa ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin Naijiria Channels TV.
Akeredolu to jẹ olori awọn Gomina Guusu-Iwọ oorun Naijiria bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ikọlu to waye si Ortom to si ni eleyi n tọka si pe nkan ko rọgbọ ni Naijiria
''Nigba ta ba n pariwo nipa pe awọn kan gbiyanju lati pa eeyan, wahala awọn janduku, jiji awọn akẹkọọ gbe,o yk ki a yara koju awọn ipenija aabo wọnyi''
O ni lootọ lasiko to fun ipese awọn ọlọpaa nipinlẹ kọọkan, ṣugbọn ki eleyi to le waye yoo ni lati gba itẹwọgba ile aṣofin apapọ Naijiria.
- Èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti náwó yàlàyòlò lábẹ́ òfin, ṣùgbọ́n ọ̀nà tí ìjọba lè gbà tojú bọ owó rẹ rèé
- Ẹnikẹ́ni tó bá fa wàhálà míì lẹ́yìn rògbòdìyàn ọ̀rọ̀ Hijab tó wáyé n'Ilorin yóò fojú winá òfin - AbdulRazaq
- Ẹ̀yà Yorùbá ti fara ṣiṣẹ́ púpọ̀ fún Naijiria, nítorí nàá à kò le déèdé sọ pé a fẹ́ kúrò - Àgbààgbà Yorùbá
- Wo àwọn ọ̀rọ̀ tó ki pọ́pọ́ tí Lateef Adedimeji fi kọrin ọjọ́ ìbí 23 fún Adebimpe Oyebade "Onítèmi"
Akeredolu sọ pe ohun ti oun lero ni pe o yẹ ki ipade waye lati koju ipenija aabo yi.
O ni lẹyin ipade wọnyi, o ṣe pataki ki awọn alẹnulọrọ tẹle abajade ipade wọn yi lati le mu alaafia ba ara ilu.
Ṣaaju ni Akeredolu ti sọ nipa awọn to n pepe si ipinya Naijiria nipa idasilẹ orileede Oduduwa Nation.
Akeredolu ko tilẹ pẹ ọrọ sọ nipa erongba yi to si ni ki awọn to n gbero rẹ ma ṣe wa si ipinlẹ Ondo nitori ti iṣọkan Naijiria lawọn n ṣe.