Sanwo-olu gifts Iya Awero house: Gbajúgbajà òṣèré, Lanre Hassan tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn ilé tuntun

Mama Awero

Oríṣun àwòrán, Kazeem Shuaib

Ẹni to ba ti fi paanu ile bo eeyan lori, gbogbo igba to ba ji laarọ, oo ni ṣẹ epe, adura lo ma maa ṣe fun un.

Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Lanre Hassan ti ọpọlọpọ mọ si Mama Awero lo fi ọrọ yii fi idunu rẹ han si gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-olu.

"Mi o mọ ohun ti mo le sọ, o ṣi n ya mi lẹnu ṣugbọn inu mi dun lonii, mi o ni le sọ pupọ. Mo dupẹ pupọ lọwọ yin gomina mi".

Àkọlé fídíò,

'Pẹ̀lú gbogbo ìrìnàjò Dubai mi, ẹ̀sẹ̀ gígún ní Nàìjíríà láti pàdé èèyàn ńlá ńlá tó lè ra àwòrán wa ṣe pàtàkì'

Iya Awero ki ẹnu bọ adura pe Oluwa a maa ran ijọba gomina Eko lọwọ ati pe Naijira ko ni bajẹ.

Gẹgẹ bi atẹjade to wa loju opo Twitter agbẹnusọ eto iroyin fun gomina ipinlẹ Eko, Gboyega Akosile, ile oniyara mẹta ni gomina fun Iya Awwero ninu Ọgba ile tuntun kan ti wọn ṣẹṣẹ ṣe ifilọọlẹ rẹ ni agbegbe Igbogbo, ipinlẹ Eko.

Ẹni aadọrin ọdun naa, Mama Awero jẹ agba ọjẹ lagbo oṣere fiimu Yoruba ati ti ede Gẹẹsi.

Lẹyin ti o tẹwọ gba kọkọrọ ile naa nibi ayẹyẹ ifilọlẹ, ṣe lo bẹrẹ si ni ṣe adura fun gbogbo awọn to pawọpọ pẹlu gomina fi ẹbun banta banta yii ta a lọrẹ.