Coronavirus updates: Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde, ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19

Makinde

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Amojuẹrọ Seyi Makinde ti darapọ mọ awọn gomina to ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni Naijiria.

L'Ọjọru ni gomina ọhun gba abẹrẹ naa to n gbogun ti aarun Corona eyii ti ileeṣẹ apoogun AstraZaneca ṣe.

Akọwe ẹka eto ilera alabọde nipinlẹ Ọyọ, Dokita Muideen Olatunji lo fun Makinde ni abẹrẹ naa ni ilu Ibadan ti i ṣe olu ilu ipinlẹ ọhun.

Lẹyin ti Gomina Makinde gba abẹrẹ tirẹ tan lo siṣọ loju lilo rẹ fun awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ, bẹrẹ lati ori awọn oṣiṣẹ eto ilera.

Ninu oṣu Kẹta ọdun 2021 yii ni wọn ko abẹrẹ ajẹsara naa wọle si Naijiria labẹ eto Covax.

Bi ẹ ko gbagbe, Ngong Cyprian ni ẹni to kọkọ gba abẹrẹ naa ni Naijiria niluu Abuja.

Lẹyin naa ni Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yemi Osibajo gba abẹrẹ ti wọn loju gbogbo ọmọ Naijiria lati ru awọn ara ilu soke lati gba abẹrẹ ọhun.

Apapọ awọn to ti lugbadi Covid-19 ni Naijiria ti le ni 162,000, awọn 148,530 moribọ lọwọ arun naa nigba ti eeyan 2,031 ti dagbere faye.

Àkọlé fídíò,

'Pẹ̀lú gbogbo ìrìnàjò Dubai mi, ẹ̀sẹ̀ gígún ní Nàìjíríà láti pàdé èèyàn ńlá ńlá tó lè ra àwòrán wa ṣe pàtàkì'