Kò sí ìjà kankan láàrí Ààrẹ Muhammadu Buahri àti Bolam Tinubu - Ìjọba àpapọ̀

Tinubu

Oríṣun àwòrán, @SaharaReporters

Eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ti gbe aadọta miliọnu naira kalẹ fun awọn oniṣowo ti ṣọọbu wọn jona ni ipinlẹ Katsina.

Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ sọ pe Tinubu bẹ ipinlẹ naa wo laarọ Ọjọru, nibi to ti parọwa si awọn oniṣowo naa lati maṣe ba ọkan jẹ lori iṣẹlẹ ọhun.

Ọpọ ọja lo jona ninu iṣẹlẹ naa, eyii to mu ki ijọba ipinlẹ ọhun gbe iwadii dide lati mọ ohun to ṣokunfa ina naa.

Ẹwẹ, ọọfisi Aarẹ Naijiria ti sọ pe ko si ija kankan laarin Aarẹ Muhammadu Buhari ati adari gbogbogbo fun ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Aarẹ Buhari, Garba Shehu fi lede, o ni irọ lasan ni awọn iroyin kan to sọ pe ija wa laarin Buhari ati Tinubu.

Oríṣun àwòrán, @SalihuAmumini

Atẹjade naa ni "ọọfisi Aarẹ fẹ fi da awọn eeyan loju pe ko si ija kankan laarin Bola Tinubu ati Aarẹ."

Àkọlé fídíò,

'Pẹ̀lú gbogbo ìrìnàjò Dubai mi, ẹ̀sẹ̀ gígún ní Nàìjíríà láti pàdé èèyàn ńlá ńlá tó lè ra àwòrán wa ṣe pàtàkì'

"Alafo diẹ to wa laarin awọn mejeji ko ṣeyin pe Tinubu kii ṣe ọkan lara awọn alabaṣiṣẹ Aarẹ."

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ahesọ ọrọ naa bẹrẹ lẹyin ti Tinubu ko ṣabẹwo si Aarẹ fun saa kan ṣugbọn eyii ko tumọ si pe ija wa laarin wọn.

O ni Aarẹ Buhari ati ẹgbẹ APC n ṣiṣẹ takuntakun ki alaafia ati idagbasoke le wa ni Naijiria.

O tẹsiwaju pe akitiyan Aarẹ Buhari lati gbogun ti iwa ajẹbanu yoo tẹsiwaju lai fi ti ahẹsọ ọrọ ti awọn madaru kan n gbe kiri ṣe.

Shehu ni Aarẹ Buhari ati Bola Tinubu jẹ ọkan gboogi lara awọn oloṣelu ti awọn eeyan bu iyi fun ju ni Naijiria.

O ni Tinubu jẹ òpó kan pataki to jẹ ki ẹgbẹ oṣelu APC di igi araba nla ni Naijiria, nitori naa, mimi kan ko le mi ibasẹpọ rẹ pẹlu Aarẹ.

O pari rẹ pe bo tilẹ jẹ pe Tinubu kii ṣabẹwo si Aarẹ loorekoore, ibaṣepọ awọn mejeji dan mọran.

Àkọlé fídíò,

Àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá kan wà tí ẹ kò lè lò pọ̀ mọ́ ara wọn, àwn ọ̀rọ̀ tẹ́ẹ lè fi rọ́pò rèé