Jimoh John Yakubu Ogi seller: Ológì déé! Ọ̀mọ̀wé nínúu kílàsìì fásitì, ológì nínú ilé

Jimoh John Yakubu Ogi seller: Ológì déé! Ọ̀mọ̀wé nínúu kílàsìì fásitì, ológì nínú ilé

Lati kekere ni Jimoh ti n lọ ogi to fi n ran iya rẹ lọwọ ni ipinlẹ Ekiti titi to fi di ẹni ọdun mọkanlelogun bayii to si jẹ akẹkọ fasiti.

Ọmọ ipinlẹ Kogi ni Jimoh ni ijọba ibilẹ Adavi.

Jimoh ni Iya oun lo kọ oun ni iṣẹ ogi ṣiṣe tori nkan to fi n tọ ohun atawọn aburo rẹ latigba ti baba rẹ ti ku niyi.

Iya rẹ ni lati ọdun marun ni Jimoh ti maa n tẹle oun lọ si ọja toi si ni titi di asiko yii oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe yatọ si ogi ṣiṣe yii, o mọwe.

Jimoh lo gba iya rẹ nimọran pe ki awọn sọ owo ogi kekeke to n ṣe di nla.

"Mo sọ fun mama pe niwọn igba ti agbara wa lara mi ti a sin ni onibara pupọ, ẹ jẹ ka maa ṣe ogi pupọ".

Yakubu ti n ta ogi rẹ kaakiri awọn ilu orilẹede Naijiria bayii pẹlu bi awọn eeyan ṣe n ri ipolowo rẹ lori ayelujara.

Ai tii si owo to to owo to le fi ra awọn irinṣẹ ti yoo sọ ileeṣẹ rẹ di nla lo ṣi n fa idiwọ fun un.