Tunde Bakare: Kìí ṣe Buhari tí mo mọ̀ lọ́dún 2011 táa jọ ń díje dupò ààrẹ ló wà níbẹ̀ báyìí

Buhari ati Pasito Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awọn ojisẹ Ọlọrun nla meji, Biṣọọbu Matthew Kukah ati Olusọaguntan Tunde Bakare tí gba aarẹ Muhammadu Buhari ni imọran lori ọrọ eto aabo to n mẹhẹ si lojoojumọ yii ati pe laipẹ olukuluku ni yoo maa ṣe ijọba ara rẹ.

Bisọọbu ijọ Aguda ẹka Sokoto lasiko iwaasu ọsẹ Ajinde sọ pe ojojumọ ni aarẹ fi n ṣe iranwọ fawọn ikọ Boko Haram ti wọn ronupiwada, ṣugbọn ti ko bikita iru ipo ti àwọn ti Boko Haram ti ṣe lọṣẹ wa.

Bakan naa ni adari ijọ Citadel Global Community Tunde Bakare ni asiko pajawiri ni ọrọ Naijiria wa bayii ati pe inu ewu nla ni eto ilera rẹ.

Kukah to pe akọle iwaasu rẹ ni, "Naijiria ki ogo to poora" lo ti salaye ààrẹ Buhari mọ pe ina nlanla ni ọrọ Boko Haram ni Naijiria lati asiko iburawọle rẹ gẹgẹ bi ààrẹ Naijiria, ṣugbọn ó fi ina naa silẹ ki o maa ran nigba ti o yẹ ki o ti pa a lasiko ti ko ti pọ.

Bakan naa lo bẹnu atẹ lu aarẹ Buhari bi o ṣe n fọwọ ra awọn Boko Haram lori pe wọn ti ronupiwada fihan gbangba gbangba pe aarẹ ko bikita nipa awọn ti iṣesi awọn ọdaran yii ti pa lara, awọn ti wọn fi silẹ lati sọfọ ẹbi wọn ti wọn pa tabi awọn to san owo gọbọi fun itusilẹ awọn eniyan wọn.

Kukah fi kun un pe iwadii kan ti wọn ṣe lagbaye laipẹ yii fi han pe Naijiria jẹ ọkan lara awọn orileede ti inu wọn ko dun lagbaye.

Àkọlé fídíò,

Jimoh Ológì déé! Ọ̀mọ̀wé ní kílàsì fásitì, ológì nílé

Kukah ni oju gba oun ti fun aarẹ fun bi ẹmi ọmọ Naijiria ko ṣe jọju pẹlu iku ojojumọ, bakan naa ni ọrọ ati iṣesi aarẹ Buhari ko jọ ara wọn pẹlu bi o ṣe leri leka lasiko to n sọ ọrọ akọsọ lẹyin ti wọn bura wọle fun un gẹgẹ bi aarẹ pe oun yoo bomi pana ikọ ọmọ ogun Boko Haram.

Bakare, to jẹ igbakeji oludije fún Buhari lasiko idibo aarẹ ọdun 2011, ṣalaye pe oun ranti bí aarẹ Buhari to dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Congress for Progressive Change (CPC) ṣe bu sẹkun nitori bi ọrọ Naijiria ṣe ka a lara to lasiko ọhun.

O ni gẹgẹ bi aarẹ ṣe sọ lọdun naa "Mo ti pinu lati lo gbogbo iyoku aye mi lati ja fun awọn eniyan orilẹede yii."

O ni o pọn dandan fun oun lati sọrọ sita nitori iru Naijiria yii kọ ni oun ati ààrẹ Muhammadu Buhari pinu lati ni lasiko ti awọn jọ n dije dupo aarẹ lọdun 2011. O ni o di tulasi lati sọrọ nitori kii ṣe Buhari yii ni oun mọ lasiko ti awọn jọ n pinu lati tun orileede Naijiria kọ.

Bakare fi kun un pe Buhari wa ninu ewu itan buburu ni Naijiria ati pe inu ewu ati pajawiri ni orile-ede Naijiria wa, idi niyi ti oun fi n sọrọ soke.