Imo State news: Aregbesola ké sí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó tú u bẹ́ láti padà wa

Rauf Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Ogundiran Dolapo

Minisita ọrọ abẹnu, Ọgbẹni Rauf Aregbesola ti kede idariji fun awọn ẹlẹwọn to salọ lasiko ti awọn agbebọn kọlu ọgba ẹwọn ipinlẹ Imo.

Aregbesola rọ gbogbo awọn ẹlẹwọn to na papa bora ni ọgba ẹwọn ilu Owerri pe ki wọn pada bibẹẹkọ wọn yoo foju wina ofin.

O ṣapejuwe ikọlu si ọgba ẹwọn Owerri gẹgẹ bi eyi to buru jai ju ninu itan.

Aregbeṣola naa yọju si ipinlẹ Imo lati wo bi nkan ṣe bajẹ to, nibẹ lo ti ni awọn to ba pada wa lai fi ipa mu wọn yoo gba idariji.

Ọgba ẹwọn

Oríṣun àwòrán, Ogundiran Dolapo

O mu iranti wa pe lasiko ifẹhonuhan #EndSARS, wọn kọlu awọn ọgba ẹwọn bii ti ipinlẹ Edo, Ondo ati Osun o si ni wọn tun gbiyanju lati kọlu ti ipinlẹ Eko naa.

O kọminu si bi wọn ṣe n ṣe ikọlu si awọn ọgba ẹwọn lẹnu ọjọ mẹta yii, o ni ijọba apapọ yoo to ṣe agbejade igbesẹ to yẹ lati ṣaabo awọn ọgba ẹwọn naa.

Àkọlé fídíò,

'Bí ojú ọ̀nà agbàrá òjò tí ijọba ṣe n'IIorin ṣe ń pa àwọn ọmọ iléèwé wa rèé! Ẹ sàánú wa'

Ọgba ẹwọn Owerri

Oríṣun àwòrán, Ogundiran Dolapo

Ẹwẹ, Aregbesola ti pinu pe gbogbo awọn ti wọn ba ko firi pe awọn lo wa nidi ikọlu naa ni wọn yoo fi panpe ofin mu ti wọn yoo si fi wọn jofin. O ni "daju daju, a o mu wọn nibikibi ti wọn ba wa".

Nibayii o ti ni ki wọn ṣe ayipada ibi ti ibi igbafẹ ilu Owerri (Owerri Recreational Club) wa to fi mọ awọn ile mii to lee koba ọrọ abo agbegbe ẹwọn ilu Owerri.

Rauf Aregbesola

Oríṣun àwòrán, @raufaregesola

Aregbesola ni o ya oun lẹnu pe wọn lee kọ ile ijo àti ọti si ọ̀ọ́kán ọgba ẹwọn nibi ti awọn to wa sibẹ ti lee lanfani lati dede ri ọna wọ inu ọgba ẹwọn naa.