Erosion in Ilorin: Kòtò tó wà níbí jìn ju ilé ìgbẹ́ lọ́! Ẹ̀mí wa ò tiẹ̀ balẹ̀ mọ́

Erosion in Ilorin: Kòtò tó wà níbí jìn ju ilé ìgbẹ́ lọ́! Ẹ̀mí wa ò tiẹ̀ balẹ̀ mọ́

Awọn ara ilu n kew gbajare si ijọba pe bi ilu awọn ṣe ri tẹlẹ kọ lo ri bayii lati igba ti ijọba ipinlẹ Kwara ti dari oju agbara ojo si ilu Abata.

"Ẹ dákun ẹ saanu wa odo o ni gbe ẹyin naa lọ o, Ọlọrun o ni ko ba ẹyin naa, ẹ ba wa bẹ awọn ijọba ki wọn ṣaanu wa.

Wọn ṣalaye pe bi awọn ọmọ ba ti wa nileewe bayii, wahala ni.

"Ọpọ igba ni agbara a ti gbe awọn ọmọ lọ to jẹ pe awa laa maa sare le wọn".

Olugbe ilu naa kan to jẹ ọkunrni sọ fun BBC Yoruba pe inu awọn dun gigi wipe BBC wa fi ọrọ wa awọn lẹnu wo'lori iṣoro to n koju ilu wọn.

"Ọsẹ ti agbara yẹn n ṣe fun wa o kọja afẹnusọ, kii dẹ ṣe ohun ti eeyan kan tabi ilu yii gan le da ṣe".

Wọn bayii kọ ni ilu awọn ṣe ri tẹlẹ, ọna ileewe yii si kọ ni oju ọna agbara wa tẹlẹ ni awọn ṣe n kigbe sita tori bo ṣe n pa eeyan ni gbogbo igba.