Èwo ló dára nínú kí kọ̀mpútà Laptop rẹ wà nínú inà tàbí kó lo bátìrì rẹ̀ bí o báfẹ́ kí ẹ̀mí bátìtì rẹ̀ pẹ́ kánrinkése?

Kọmputa alagbeletan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ibeere ti ọpo maa n fẹ lati beere tọrọ ba dọrọ lilo ẹrọ kọmputa alagbeka Laptop ni bi wọn ṣe le loo ti batiri rẹ yoo si jẹ bẹmidije ti ko si ni maa ku pi-pi-pi ni dakudaji.

Lootọ gbogbo batiri lo maa n padanu agbara rẹ bi ọjọ ba ṣe n gori ọjọ ti wọn si n loo, sibẹ bi eeyan ba ṣe lo batiri tabi tọju batiri kọmputa alagbeka rẹ si yoo tun ṣalaye bi emi rẹ yoo tun ṣe gun si pẹlu.

To ba ri bẹẹ, bawo la ṣe lee tọju batiri kọmputa alagbeka Laptop wa?

Lọna miran, ṣe ki a maa ri daju pe o n gba ina sara de iwọn ọgọrun ninu ọgọrun 100% ni tabi ki a maa paa ka tun tan an gẹgẹ bi ina ara rẹ ba I ṣe n lọ silẹ sii?

Ọpọ awọn akọṣẹmọṣẹ ti BBC News Mundo ba sọrọ woye pe ọna to dara julọ lati lo batiri rojẹ pe eroja lithium.

Bi ọdun ṣe n gori ọdun ni imọ ijinlẹ nipa batiri ṣise n goke sii.

Amọsa nigna to di bii ọdun mẹwaa sẹyin lo di wipe agbara awọn batiri kọmputa alagbeka Laptop wọnyi ko fi bẹẹ dara to mọ lẹyin ti wọn ba ti tii bọ ina mọnamọna fun igba ọgọrun ni ọrọ ti Ashley Rolfe, ọga agba ẹka imọ ẹrọ ni ileeṣe Lenovo ni orilẹede Ireland ati ilẹ Gẹẹsi sọ fun BBC Mundo.

Àkọlé fídíò,

Ẹ wo àrà àwọn ọmọ kékeré ń fi ẹ̀kọ́ kọ̀mpútà dá

Jijafafa awọn batiri kọmputa bayi kii ju ọdun mẹta si marun un lọ mọ bayii ti ko si kagbara lati gba ju ki wọn tii bọ ina laarin igba ẹẹdẹgbẹta si ẹgbẹrun kan lọ.

Kent Griffith, oluwadi ijinlẹ nipa imọẹrọ nipa ohun amuṣagbara ni fasiti Northwestern University lorilẹede Amẹrika fidi eyi mulẹ fun.

Bawo ni a ṣe le ṣe eyi ko fi jọ ara wọn?

Fifi kọmputa alagbeka Laptop silẹ sinu ina lẹyin ti ina ori batiri rẹ ba ti wọ ida ọgọrun dara pupọ, koda ko s'ohunto buru rara nibẹ gẹgẹ bi Ọgbẹni Rolfe lati ileeṣẹ aṣekọmputa Lenovo ṣe fi to BBC Mundo leti.

Àkọlé fídíò,

Child Engineer: Olamide Odukọya nílò ìrànlọ́wọ́ láti lọ síléẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ

Awọn kọmputa alagbeka Laptop lati ileeṣẹ Lenovo atawọn ileeṣẹ miran a maa lo awọn eroja ignalode sẹnsọ ti yoo rii daju pe batiri ko gba ina sara tabi gbona ju bi o ti yẹ lọ.

Amọsa, "ririi daju pe batiri wa ni ida ọgọrun 100% nigba gbogbo yoo mu adinku diẹ ba ẹmi gifun batiri bẹẹ."

Alabaṣiṣepọ rẹ, Phil Jakes to jẹ oludari ẹka imọ ẹro to lamilaaka, tosi tun jẹ agba ọjẹ onimọ ẹrọ ni ileeṣẹ Lenovo fọwọsi ohun to sọ.

"Pẹlu iwadi ti a n ṣe lati bii ọdun diẹ sẹyin, a ti rii peẹmi batiri kọmputa a maa tete ge kuru bi o ba ti n fi igba gbogbo wa ninu ina, paapaajulọ ti oru ba tun wa nibẹ pupọ.

" O dara ki agbara ina to wa lori batiri kọmputa rẹ o wa ni ida aadọta ninu ọgọrun 50% nitori igba ti wọn ba wa ni ida ọgọrun 100% tabi odo 0% ni ọrun maa n wọ wọn julọ.

Idi niyi tawọn onimọerọ maa fi n daa laba pe ki o wa laarin ida ogun 20% si ida ọgọrin 80%" ni alaye ati amọran ti Ọgbẹni Rolfe ṣe.

Bakan naa ni ileeṣẹ Microsoft pẹlu ṣekilọ loju opo ayelujara wọn pe ni ti awọn ẹrọ kọmputa alagbeka ti awọn ba ṣe o, "bi eeyan ba n ti batiri bọ ina nigbagbogbo, irufẹ batiri bẹẹ yoo tete padanu agbara rẹ."

" Ẹ le ran wa lọwọ lati ṣẹgun eyi nipa riri daju pe ẹ ko fi komputa alagbeka Laptop yin si ẹnu.ina.mọnamọna fun igba pipẹ."

Bawo ni a ṣe wa lee lo ẹrọ kọmputa alagbeka wa ni alopẹ kanrinkese?

Awọn amọran wọnyi ko wa ni didan ki o maa fa waya ina kọmputa alagbeka rẹ yọ ni kete to ba tiwọ ọgọrun 100% .

"Gbogbo awọn ẹrọ kọmputa alagbeka lo ni eroja lati daabo bo batiri rẹ lọwọ gbigba ina sara ju ṣugbọn o lee mu ki ẹmi batiri kọmputa rẹ gun sii nipa riri daju pe ida ọgọrin 80% lo n wa." Ni amọran ti Rolfe lati ileeṣẹ Lenovo gbe kalẹ.