Yoruba film celebrities: Ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀ nílé Wasiu Alabi Pasuma

Igbeyawo ọmọ Pasuma

Oríṣun àwòrán, PAsuma. Jaiye Kuti

Ọpọlọpọ òṣèré fiimu ati olorin Yoruba lo n kan sara si gbajugbaja olorin Alhaji Wasiu Alabi Pasuma fun oriire ati aṣeyọri igbeyawo ọmọ rẹ to fi fun ọkọ l'Ọjọbọ ọsẹ.

Awọn oṣere fiimu Yoruba yẹ Ọga Nla si gidi gan gẹgẹ bi ọkan lara wọn ati ẹni ti wọn bọwọ fun.

Lara awọn to fi fidio ati aworan bi eto naa ṣe n lọ si ori ayelujara wọn lati ki Pasuma si ni oṣere Jaiye Kuti nibi ti oun, Ayo Adesanya ati Faithia Williams ti jọ joko.

Oríṣun àwòrán, Jaiye Kuti

Bakan naa lo tun fi fidio kan sita to n safihan awọn akẹgbẹ wọn miran to wa nibi igbeyawo naa. Lara wọn ni Madam Saje, Jigan, Mama Rainbow ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, officialpasuma/instagram

Ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀ nílé Wasiu Alabi Pasuma, ọmọ rẹ̀ obìnrin ń relé ọkọ

Orin ayọ, ati ijo idunnu lo n rọ bi ojo ni ile gbajugbaja olorin Fuji, Alhaji Wasiu Alabi Pasuma, pẹlu bi o ṣe fa ọkan lara awọn ọmọbinrin rẹ fun ọkọ.

Ọjọbọ ni agba olorin naa fi sori ayelujara Instagram rẹ pe ọmọ oun, Oyindamola ti di ọlọkọ.

Ilu Eko ni ayẹyẹ naa ti n waye lọwọlọwọ.

Ninu ọrọ naa to kọ si abẹ fidio kan to ṣafihan bo ṣe n fa ọmọ rẹ wọ inu gbọngan igbeyawo, ni Alhaji Pasuma ti sọ pe ẹwa ati ipenija to wa ninu jijẹ obi ni pe, ko si bo se wu obi ki ọmọ rẹ o wa pẹlu rẹ to ni igba gbogbo, awọn asiko kan yoo wa ti obi ni lati jọwọ ọmọ rẹ ko lọ.

Àkọlé fídíò,

Torí àti ṣe Kòkò irin, bí mo ṣe máa ǹ fara yá iná nìyìí - Amokoko Saki

Oríṣun àwòrán, officialpasuma/instagram

"O ti wa a ye mi wayii pe ko si nkan to dabi ki eeyan ri ọmọ rẹ ikoko, ko dagba, ko tun wa wọ aṣọ igbeyawo lọjọ ẹyẹ rẹ.

"Ha, ko si ibaṣepọ to da bii ti baba ati ọmọ rẹ obinrin."

Pasuma tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe asiko ti ọmọ ba n ṣe igbeyawo jẹ akoko idunnu fun gbogbo obi.

"Yiyọnda ọmọ rẹ obinrin, kii ṣe nkan to rọrun rara, ṣugbọn o jẹ nkan ti ko ṣee ma ṣe, bo ti wu ki o gbiyanju lati sa fun asiko naa."

Oríṣun àwòrán, city people tv/instagram

Baba iyawo naa wa gbadura pe ki idunnu nla ko wa pẹlu tọkọtaya, ki igbeyawo wọn si jẹ apẹẹrẹ fun awọn to wa ni ayika Oyindamola ati Olajuwon, pe nkan to rẹwa ni ifẹ, to si jẹ alaanu ati olufarada.

Ilana ẹsin Islam ni ayẹyẹ igbeyawo naa fi waye.

Oríṣun àwòrán, officialpasuma/instagram

Lara awọn gbajumọ to ti peju sibi ayẹyẹ igbeyawo naa ni Mama Rainbow, Yomi Fash Lanso atawọn eekan oṣere ati olorin Yoruba.