Àwọn ọmọ ìjọ RCCG mẹ́jọ tó bọ sí ọwọ́ ajínigbé ní Kaduna ti gba òmìnira

Adeboye

Oríṣun àwòrán, @thesignalng

Awọn ọmọ ijọ Redeem mẹjọ ti awọn ajinigbe gbe ni ipinlẹ Kaduna ni oṣu to kọ ja ti gba ominira.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2021 ni awọn eeyan naa to jẹ ọmọ ijọ RCCG Trinity Sanctuary, Kaduna, di awati lẹyin ti awọn ajinigbe kọlu wọn ni opopona Kachia si Kafanchan.

Iroyin sọ pe wọn n rinrinajo fun eto isin ọdun ajinde ni awọn ajinigbe da wọn lọna.

Ṣaaju si ni awọn ajinigbe naa ti beere fun aadọta miliọnu Naira, fun itusilẹ wọn.

Ṣugbọn ninu ikede kan to fi si ori ayelujara Twitter rẹ, Pasitọ Agba ijọ Redeemed Christian Church of God, Enoch Adeboye, sọ pe awọn eeyan mẹjọ naa ti gba ominira.

O fikun ọrọ rẹ pe gbogbo wọn lo ti wa ni ileewosan fun ayẹwo ati itọju ara wọn.

Pasitọ Adeboye sọ pe "ogo ni fun Jesu".

Bakan naa lo gbadura pe ki alaafia jọba ni gbogbo ibit i wahala ti n waye ni orilẹ-ede Naijiria.