Baba Ijesha: Ọ̀rọ̀ di gbas gbos láàrin àwọn aráàlú àti agbẹjọ́rò Ogunlana lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha

Agbẹjọro Ogunlana ati Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Adesina Ogunlana

Agbẹjọro Ogunlana ti oun ati gbajugbaja oṣere Yomi Fabiyi ki ara bọ jija fun ẹtọ Olanrewaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijesha ti fesi lori iroyin pe oun kii ṣe agbẹjọro fun Baba Ijesha.

Ninu fidio to fi sita lori ayelujara, ṣe lo n kọ ẹrin lakọ lakọ to fihan pe yẹyẹ lasan lasan ni ọrọ to n fo kaakiri ori ayelujara yii.

"Gbogbo ẹni to ti n yọ suti ete pe Ọlọrun ti mu mi, ko mọ ẹni ti wọn ko rara, bi ikun lo lọ oko bi Fadẹru ni, ipade doju ala, wọn ti fọwọ wu ṣonṣo wọn a si pade ṣonṣo".

Bo tilẹ jẹ wipe ao ri oju Baba Ijesha pe o sọ ọrọ sita pe Ogunlana kọ ni agbẹjọro oun, awọn iwe iroyin n gbe e sita pe agbẹjọro kan ti wọn ni oun ni ti Baba Ijesha, Kayode Olabiran lo fi atẹjade sita lorukọ onibara rẹ pe:

"Mo fi asiko yii jẹ ko di mimọ ti mo si tẹpẹlẹ mọ ọ pe, mi o figba kankan ṣalaye ohunkohun fun agbẹjọro Ogunlana tabi fun laṣẹ lati gbe ogbesẹ lorukọ mi".

Àkọlé fídíò,

Mo dúpẹ́ pé ìgbà tí mo wà nínú Jesu ni mo lọ sẹ́wọ̀n, tó bá jẹ́ pé mo wà nínú áyé ni ... - Wòlìí Genesis

Iroyin naa tun ni Baba Ijesha sọ pe "Ogunlana kii ṣe agbẹjọro mi, ohunkohun tẹẹ ba si gbọ latẹnu rẹ nipa awọn agbẹjọro mi tabi ẹjọ to wa niwaju ọlọpaa tabi ile ẹjọ yii kii ẹ otitọ".

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Olabiran tun ni ikọ kan lati ẹka ẹgbẹ awọn amofin Naijiria lẹka idajọ ipinlẹ Eko ati ileeṣẹ to n ri si eto ofin lo gba beeli Baba Ijesha lọjọ kẹtadinlogun oṣu karun.

Lọ̀rọ̀ ba di hun hun hun lori ayelujara ti awọn eeyan si n beere pe taa gan ni agbẹjọro Baba Ijesha atipe awọn eeyan bẹrẹ si ni kan si Ogunlana to jẹ agbẹjọro akọkọ to kọkọ bọ sori ọrọ yii.

Oríṣun àwòrán, Adesina Ademola Ogunlana

Ẹwẹ, Ogunlana bu sẹrin keekee to si ni ki awọn eeyan ba oun rẹrin ni "emi Ṣẹrubawọn Adesina, ẹ o mọ ẹni ẹ ko ni Baba Ijesha n sọ pe oun ko mọ".

O dupẹ lọwọ awọn to kan si oun o si ṣalaye bi Ọlọrun ṣe ran wọn lọwọ lati ri beeli naa gba nipasẹ Majisireetiu lọjọ Aje ọsẹ to kọja ti gbogbo eeyan gan si n ba awọn yọ lori aṣeyori nla yii.

Ogunlana ni gbogbo awọn to wa nidi ọgbọn alumọkọrọyi ti wọn n lo yẹn ko mọ Adesina Ademola Ṣerubawọn Ogunlana, to si ni wọn yoo gburo latọdọ oun lọjọ Aiku.

Àkọlé fídíò,

Àìsàn jẹ́ kí àwọ̀ ara Amida dàbí ara ẹja

"Baba ijesha lee ni haa, Ogunlana o, emi mo gba ẹ ni agbẹjọro mi amọ o ti pọju fun mi tabi o ti gbona ju torinaa mi o lo ẹ gẹgẹ bii agbẹjọro mi mọ amọ o da mi loju pe ko le layelaye, ko sọ bẹẹ, ko si ni dan an wo lati sọ pe oun ko mọ emi Adesina Ademola Ogunlana ri tabi ṣalaye ohunkohun fun mi".

O ni "mo le fi daa yin loju pe arumoloju lasan ni gbogbo nkan ti ẹ n ri lori ayelujara, mo n sọ fun un yin pe awọn kan yoo gboorun ara wọn lọla".

Ogunlana ni oun kan sọ ọrọ kekere eleyi jade lati fi tọ ọ yin lẹnu wo ni, kesekese ṣi n bọ lọna tori gbogbo nkan to n ṣẹlẹ yẹn kan jẹ awọn iwa arumọloju laarin awọn ọlọpaa tabi lẹka ofin ni.

Ọwọ sinkun ofin tẹ Baba Ijesha ni nkan bi oṣu kan o le lori ẹsun ifipaba ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹrinla kan lopọ to jẹ ọmọ agbatọ akẹgbẹ rẹ, Princess Comedienne.

Ni bayii, ko tii si iroyin pe o ti jade kuro latimọle lẹyin ọjọ ti wọn ti gba beeli rẹ.