China ultramarathon: Òjò àrọ̀rọ̀dá gbẹ̀mí àwọn ènìyàn 25 tó ń ṣeré ìdárayá

China

Oríṣun àwòrán, STR/AFP via Getty Images

Awọn elere idaraya ori papa mọkanlelogun ti ku lorilẹede China lẹyin ti iji lile deede bẹrẹ lasiko ti wọn sare oni ọna gigun ni iha ariwa orilẹede naa.

Iji lile naa to mu ojo arọrọda dani to to iwọn kilo mita ọgọrun un 100km (60-mile), in agbegbe Gansu ni opin oṣẹ.

Pẹlu ayọ ati idunnu ni awọn elere idaraya naa fi tu yaya-tu yaya jade ni ọjọ Satide, ti wọn si wọ aṣọ penpe pẹlu asia idije ere idaraya naa.

Amọ, ko i tii ju wakati mẹta ti idije naa bẹrẹ ni iji lile bẹ silẹ, ti ojo lile si tẹre, eleyii to fi mu ki oju ọjọ tutu ju bo ṣe yẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, STR/AFP via Getty Images

Amọ awọn elere idaraya to kopa ninu idije naa ni lọwọ aarọ ni oju ọjọ ti fihan pe ojo diẹ le rọ, amọ ko sẹni to sọ fun wa pe ojo naa yoo pọ to bẹẹ.

Awọn alakoso ere naa da a duro nigba ti awọn eniyan to le ni mejilelaadọsan ninu awọn elere naa di awati, ti wọn si bẹrẹ si ni wa wọn.

Oríṣun àwòrán, CCTV via Reuters

Lara awọn ti wọn ri ninu awọn to sọnu naa ni otutu aya pẹlu aisan ti dede kọlu wọn lasiko ti wọn n wa wọn.

Awọn olotu eto ilera lorilẹede naa ni eniyan mọkanlelaadọjọ ni wọn ti wa ni alaafia bayii, ti mẹjọ ninu wọn si farapa.

Ọkan lara awọn to jajabọ ninu iṣẹlẹ naa ni bi oun ṣe ri pe ojo naa n pọsi, ni oun ti yipada lọ si inu ile itura ohun, to si jawọ ninu idije naa.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ni awọn oṣiṣẹ pajawiri ti bẹrẹ si ni wa awọn eniyan to ṣọnu sinu iji lile naa pẹlu ohun elo igbalode ti wọn fi wa wọn.

Amọ, awọn araalu koju oro si iṣẹlẹ yii ti wọn si dẹbi ru ijọba wi pe ko bojuto ere idaraya naa nipa pipese ohun idaabobo fun awọn to n kopa ti ohunkohun ba sẹlẹ.