Abayomi Dairo Military Plane crash: Mọ rọ̀ pé ó tí tán fún mí ní nígbá tí àwọn agbẹ́bọ̀n já ọkọ̀ bàálú mí bọ̀, tí wọ́n sí dojú ìbọn bò mí!

Abayomi Dairo

Oríṣun àwòrán, Others

Ọmọogun ofurufu Naijiria, Abayomi Dairo ti sọ iriri rẹ lọwọ awọn agbẹbọn to ja ọkọ ofurufu rẹ bọ ni ipinlẹ Zamfara ti ikọ ọmọogun ofurufu ti lọ koju wọn.

Ọmọogun Dairo lo sọ iriri rẹ fun awọn akẹgbẹ, ọrẹ ati ojulumọ rẹ lẹyin to de ibugbẹ awọn ọmọogun ofurufu to wa ni Kaduna.

Ileeṣẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria ni Ọjọ Kejidinlogun, Osu Kẹjọ , ọdun 2021 ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti awọn agbẹbọn ja ọkọ ti ọmọogun wa ninu rẹ bọ, amọ ti ọmọogun naa jajabọ lọwọ awọn agbebọn naa.

Dairo lasiko to n ba awọn eniyan rẹ sọrọ ni Ọlọrun lo ko oun yọ ninu ewu naa nitori ọpọlọpọ igba ti oun salọ ninu igbo ni oun sọ irẹti nu pe o ti tan, amọ Ọlọrun ko oun yọ ti oun si dele ni ayọ ati alaafia.

'' Ki iṣẹlẹ yii to waye ni mo ti n la ala to n bani lẹru fun ọjọ diẹ wi pe mo wa loju ogun ti awọn ọta si yi mika, ti wọn doju ija kọmi loju ogun''

Nitori naa nigba ti awọn agbebọn yii bẹrẹ si ni yin ibọn pẹlu ado oloro lu ọkọ baalu mi, ti ijanu ọkọ ofurufu mi si kọ iṣẹ silẹ,ko si ohun ti mo le e ṣe mọ yatọ si ki n bọ silẹ ninu ọkọ ofurufu naa.''

Wẹrẹ ti mo bọ silẹ bayii, ti awọn agbebọn naa ri mi, ti wọn si bẹrẹ si ni le mi ni mo sọ wi pe Ọlọrun, ni ọwọ rẹ ni mo fi ẹmi mi le...ti mo si bẹrẹ si sare kikan kikan fun ẹmi mi

Oríṣun àwòrán, Others

''Ọrọ ẹri mi ni pe Ọlọrun gba mi la lọwọ awọn agbebọn yii nitori o fun mi ni okun ati agbara lati sa asala fun ẹmi mi, nitori o le ni kilomita ọgbọn ti mo fi sare.''

''Mi o le ka iye igba ti mo subu sinu akekee pẹlu ibẹru pe ki awọn ẹranko oloro ma jade si mi ninu igbo''

''Ohun ija to wa lọwọ awọn ọdaran yii ju ki a pe wọn ni agbebọn lọ, wọn ti da agbẹsunmọmi''

Ọmọgun Abayomi Dairo ni ọpọ igba ni awọn agbebọn yii koju oun ni oju koroju amọ ti oun si jajabọ kuro lọwọ wn nitori oun ti wọn fẹ ṣe ni ki wọn mu oun laaye gẹgẹ bi ọmọogun ju ki wọn pa oun lọ.

Dairo fikun pe ohun ija to wa ni ọwọ awọn agbebọn ju kekere lọ, ti wọn si ti sọ ara wọn di agbesunmọmi lorilẹede Naijiria.

''Mo dupẹ lọwọ̀ ileeṣẹ ikọ ọmọogun Naijiria to doju kọ awọn agbebọn wọnyii nigba ti mo n salọ, eleyii to jẹ ki n ri aye fi ara pamọ.''

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Bakan naa ni Ọmọogun Abayọmi dupẹ lọwọ awọn araalu to gba oun si ile, ti wọn fun oun ni aṣọ, ounjẹ ati oogun, ti wọn si mu ohun lọ si ọdọ Emir wọn, to pe ileeṣẹ ọmogun to wa ni agbegbe naa, ti wọn si dọọla ẹmi oun.

''Lati ibẹ ni ọkọ ofurufu ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ti wa gbe mi, ti mo si de ile ni ayọ ati alaafia''.

''Igba ti mo dele ni gbogbo egungun ara mi ati awọn ibi ti mo ni ipalara bẹrẹ si ni dun mi, amọ mo dupẹ lọwọ Ọlọrun ati awọn ẹbi ati ọrẹ ti wọn gbadura fun mi ni gbogbo igba ti mo fi wa ninu igbo.''

''Adura yii pẹlu oun to ki mi laya, ti mo fi mu ọkan le''