Ibrahim Elzakzaky: Kí ni àwọn ẹ̀sun tuntun tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna tún gbé dìde tako Ibrahim El-zakzaky, olórí ìjọ Mùsùlùmí Shiite ní Nàìjíríà?

Ibrahim El-zakzaky

Oríṣun àwòrán, other

Lẹyin ọjọ meji ti ile ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Kaduna yọ ọrọ ẹjọ lọrun aṣiwaju ijọ Islamic Movement of Nigeria, IMN Sheikh Ibrahim El-zakzaky, ijọba ipinlẹ Kaduna tun ti n gbe awọn ẹsun miran dide.

Ẹsun ẹjọ meje ọtọọtọ miran ni wọn tun gbe dide tako Sheikh El-zakzaky niwaju ile ẹjọ giga apapọ kan.

Olupẹjọ agba fun ijọba ipinlẹ Kaduna, Daris Bayero ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin Channels pe lara awọn ẹsun tuntun ti wọn fi kan olori ẹsin naa ni igbesunmọmi, kikọju ija si ijọba ipinlẹ naa ati ijọba apapọ.

Àkọlé fídíò,

Bí ìjọba bá kọ̀ tí kò ṣèdájọ́, tí Ọlọ́pàá kọ̀ pé àwọn kọ́ ló paá, ẹni tó pa ọmọ mi, náà máa ...

O ni awọn kan lara ẹsun tuntun ti wọn fi n kan an jẹyọ lati ara awọn ohun to ti n ṣe ṣiwaju ọdun 20215.

Amofin Bayero ni o di dandan ki ile ẹjọ gbe aṣẹ tuntun fun mimu Sheikh El-zakzaky kalẹ lati lee wa dahun si awọn ẹsun naa.

Lati nnkan bii ọdun mẹrin bayii ni olori ijọ ẹsin musulumi Shiite lorilẹede Naijiria naa ti n jẹjọ pẹlu iyawo rẹ Zeenat lori awọn ẹsun bii dida alaafia ilu ru, pipejọpọ lọna ti ko tọ ati awọn ẹsun mẹjọ miran to da le ipaniyan.

Amọṣa ni Ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn ọdun 2021 ni Onidajọ Gideon Kurada dajọ pe ẹsun ti wọn fi kan oun ati iyawo rẹ ko lẹsẹ nlẹ.

Àkọlé fídíò,

Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'