Ibadan shoprite killing: Ọmọ tí mo tọ́ tí mo mọ̀ f'ọ́dún 21, bí wọ́n ṣe wá bá igbó lápò rẹ kò yé mi - Iya Akintunde

Ibadan shoprite killing: Ọmọ tí mo tọ́ tí mo mọ̀ f'ọ́dún 21, bí wọ́n ṣe wá bá igbó lápò rẹ kò yé mi - Iya Akintunde

Abiyamọ ku ọrọ ọmọ. Ki Eleduwa ma jẹ ka foju sunkun ọmọ ni adura ti ọpọ maa n gba ṣugbọn eyi jẹ ọrọ latẹnu mọlẹbi Akintunde o si ẹnikẹni to pa wọn lọmọ niwọn igba ti wọn ni awọn Ọlọpaa ko mu otitọ ibẹ jade sita.

Iroyin naa kan kaakiri lati ọsẹ tó kọja wọ gbogbo ọsẹ yii pe wọn dede ṣekupa ọdọkunrin akẹkọjade ileẹkọ gbogbonṣe Poly Ibadan kan ti orukọ rẹ n jẹ Akintunde Babatunde.

Iya rẹ sọ ninu ifrọwanilẹnuwo nigba ti BBC Yoruba ṣe ibẹwo si ile wọn pe ko pe iṣẹju ọgbọn rara ti Akintunde ni oun fẹ lọ ra nkan ni ile itaja nla Shoprite ni ọrẹ rẹ pe oun lori foonu pe ọlọ́paa ti yinbọn pa Akintunde. Èyí ni bí wọ́n ṣe pa akẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan tí wọ́n sì sọ òkú rẹ̀ sí orí àkìtàn

Ọgbẹni Waheed Akinola to jẹ baba Akintunde sọ fun wa pe oun ti gba kamu. Ni tirẹ, gbogbo ohun to ṣokunkun, kedere ni niwaju Ọlọrun, o ni oun ko mọ ọmọ oun ni amugbo tabi ẹlẹgbẹ okunkun gẹgẹ bi esi ti wọn gba latọdọ Ọlọpaa.

Ẹwẹ, nigba ti BBC yoo fi kan si ileeṣẹ Ọlọpaa, wọn kọjalẹ pe irọ patapata gbaa ni, awọn si kọ ni awọn pa Akintunde.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣọ pe awọn ọlọpaa yinbọ fun ọdọkunrin naa lasiko ti ko fẹ fi jọwọ ara rẹ silẹ fun ọlọpaa ti wọn ko wa ṣọ ọgba ile itaja nla naa.

Ṣe ni ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, latẹnu alukoro wọn Adewale Oṣifẹsọ ni ijiya awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ni o fa iku rẹ atipe iwadii ṣi n lọ lọwọ sii.

Taa ni ka wa gbagbọ pẹlu bi awọn mọlẹbi ṣe n wa omije loju fi fọwọ sya iru eeyan ti ọmọ wọn yii to jẹ ọmọ ọdun mọkanlelogun jẹ́ ti ọpọ si n jẹri wi pe "bi ẹ ba bu omi si Akintunde lẹnu, ẹ o ṣi baa lẹnu rẹ bẹẹ ba pada de".