Ajogbajesu Twins: Wo ohun tí àwọn èèyàn ń sọ nípa ikú Tope Ajogbajesu Twins to dágbére f'áyé

Tope, kan lara awọn Ajogbajesu Twins

Oríṣun àwòrán, Ajogbajesu Twins/Facebook

Kete ti ikede iku Tope ọkan lara awọn olorin Kristẹni, Ajogbajesu jade l'ọjọ Ẹti, gbogbo ori ayelujara kun fun ọrọ iyalẹnu ati idagbere fun awọn to sunmọ oloogbe bi iṣa ọrun.

Lara iroyin taa gbọ ni pe ọgbẹ inu, iyẹn Ulcer lo ṣeku paa tori o ti wa lori akete aisan fun igba diẹ bayii gẹgẹ bi ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ awọn olorin yii ṣe sọ fun BBC Yoruba.

Ọpọ awọn akẹgbẹ wọn ati ololufẹ wọn lo ti n sọ ero wọn ati ọrọ idagbere lati igba naa. Lara wọn ni gbajugbaja olorin Lanre Teriba ti ọpọ mọ si "Atorise " to jẹ pe lori ohun to kọ sita, awọn eeyan ṣi n sọrọ loju opo rẹ nipa oloogbe.

Oríṣun àwòrán, Lanre Teriba/Facebook

Bakan naa loju opo awọn ololufẹ olorin mii Evangelist Dr Dare Melody, ero ko gba ẹsẹ ọrọ ikẹdun nibẹ pẹlu bi ọrọ̀ naa ṣe ka gbogbo eeyan lara.

Oríṣun àwòrán, Dare Melody Fans Page

"Latigba ti mo ti wa nile ẹkọ girama ni mo ti jẹ ololufẹ yin... Mo nifẹ rẹ Tope ṣugbọn Ọlọrun fẹ ọ ju. Sun re o!

Loju opo awọn Ajogbajesu gangan ni oniruuru ọrọ bi eyi ti n jẹ jade ti awọn eeyan n sọ iriri wọn pẹlu awọn ibeji yii.

Àkọlé fídíò,

Bí ìjọba bá kọ̀ tí kò ṣèdájọ́, tí Ọlọ́pàá kọ̀ pé àwọn kọ́ ló paá, ẹni tó pa ọmọ mi, náà máa ...

Oluwaleye Taiwo ni "eyi dun mi gidi gan o, a ṣi jọ wa pap ni ọjọ mẹta sẹyin ni Akure ni".

Awọn Ajogbajesu Twins ṣẹ ṣe awo orin kan amọ ti ikeji rẹ ni ko duro wo agbejade rẹ eyi ti wọn ṣẹṣẹ kọ pẹlu Aafaa ẹsin Islam kan, Alhaji Mustapha Abiola ti wọn pe akọle rẹ ni ounjẹ Ọlọhun.

Oríṣun àwòrán, Ajogbajesu Twins

Oríṣun àwòrán, Ajogbajesu