Tinubu death: Asiwaju ò kú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí nílé ìwòsàn ṣùgbọ́n kò sí ní Naijiria - Tunde Rahman

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Tunde rahman

Agbẹnusọ eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu, iyẹn Tunde Rahman ti sọ pe ko si ootọ ninu iroyin to sọ pe eekan oloṣelu naa ti jade laye.

Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Abamẹta, Rahman ni alaafia ni Tinubu wa bẹẹ ni ko ṣaisan kankan.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, o ni Tinubu ko ṣaisan, bẹẹ ni ko si ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun bi awọn eeyan kan ṣe n sọ.

O ni "Asiwaju Bola Tinubu ko ṣaisan, bẹẹ ni ko si nile iwosan nitori ko ṣe ailera ti yoo mu ko dero ile iwosan."

Rahman sọ pe lootọ ni eekan ẹgbẹ oṣelu APC ọhun ko si ni Naijiria lọwọ yii, ṣugbọn yoo pada wa si Naijiria laipẹ jọjọ.

O tẹsiwaju pe "Gbogbo igba ti Tinubu ba ti tẹkọ leti lọ silẹ okeere ni awọn kọlọrọsi kan maa n sọ pe o ti dubulẹ aisan tabi pe o ti jade laye."

Àkọlé fídíò,

Bí ìjọba bá kọ̀ tí kò ṣèdájọ́, tí Ọlọ́pàá kọ̀ pé àwọn kọ́ ló paá, ẹni tó pa ọmọ mi, náà máa ...

"O ṣeni laanu pe ni gbogbo igba ti wọn ba ti n gbe ahesọ iroyin bẹẹ , otitọ ṣi maa n jade pe irọ ni wọn n pa sibẹ, wọn kọ lati jawọ."

Rahman pari ọrọ rẹ pe ọwọ Ọlọrun ni ẹmi gbogbo eeyan wa, niroti naa ko si ẹni to le sọ igba ti ẹnikẹni yoo fi aye silẹ ayafi adaniwaye nikan.

Bi ẹ ko ba gbagbe, kii ṣe igba akọkọ ree ti iroyin yoo gbode kan pe gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri naa ti jade laye ṣugbọn ti ọrọ ko ri bẹẹ.

Àkọlé fídíò,

Kemi Olunloyo on Sunday Igboho: Mi ò gbè lẹ́yìn Yoruba Nation àmọ́ mo wà lẹ́yìn Sunday Igb