Saraki EFCC arrest 2021: Fúnrara Bukola Saraki ló lọ sí EFCC láti lọ yanjú ọ̀rọ̀ ara rẹ̀- Agbẹnusọ Saraki

Saraki

Oríṣun àwòrán, @Others

Saaju ni iroyin ti kọkọ jade pe ọwọ ajọ EFCC ti tẹ Oloye Bukola Saraki.Bukola Saraki ti wà ní àhámọ́ àjọ EFCC

Iyen nigba ti Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria, EFCC ti sọ pe Aarẹ ile igbimọ aṣofin Naijiria tẹlẹ, Bukola Saraki ti wa ni ahamọ awọn.

Agbẹnusọ ajọ naa, Wilson Uwujaren sọ fun BBC pe awọn lo fi iwe pe Saraki, ṣugbọn ko ṣalaye eredi ti wọn ṣe fi iwe pe Saraki ni ẹkunrẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, Others

Sugbon bayii ni agbenuso fun Bukola Saraki lori eto ifitonileti ati iroyin, Yusuph Olaniyonu ti fi atẹjade sita lori iṣẹlẹ naa.

Ninu atẹjade naa ni Ogbeni Yusuph ti salaye pe, funrare Bukola Saraki lo fi ẹsẹ ara rẹ rin lọ si ọgba ajọ EFCC lati lọ yanju ọrọ naa kii ṣe pe EFCC mu u.

Ninu atẹjade ti Yusuph buwọlu naa lo ti slaye pe nitootọ ni awọn ajọ EFCC ni ibeere fun Bukola Saraki.

O ni pe Saraki funra rẹ lo lọ sibẹ lọ yanana ọrọ to nii ṣe pẹlu aṣẹ ileẹjọ giga l'Abuja.

Àkọlé fídíò,

Silas Robotic Engineer: Kò sí ǹkan rere tí ọmọ Nàìjíríà kò lè ṣe

Yusuph ni bayii Saraki ti pada sile, ajọ EFCC ko mu u silẹ ni atimọle gẹgẹ bi awọn iroyin kan se n gbe kiri.

Oríṣun àwòrán, @Yusuph

Yusuph to jẹ agbẹnusọ fun Bukola Sarakisọ pe lọjọ kẹrinla, oṣu keje, ọdun yii ni wọn beere fun aṣẹ lati ṣiṣẹ wọn lọdọ Adajọ nile ẹjọ giga naa.

Iroyin ni lori iṣẹ akanṣẹ awọn agbaṣẹse bilionu mẹrindinlọgbọn naira ni ọrọ naa da le lori lori iṣẹ akanse laarin ọduin 2011 si 2019.

Àkọlé fídíò,

E jẹ́ ká lọ sí ìlú mi BBC yìí dá lórí Epe ní bi tí eégún ti ń fi ẹgba dá bírà lára Oba

Yusuph ni pe Bukola Saraki ti dahun ibeere ajọ EFCC, o si ti pada sile rẹ.

O ni ko si ẹni to fi Saraki si atimọle lori ọrọ naa.

Bakan naa ni Yusuoh ni pe Saraki setan lati maa yọju si ajọ EFCC lati salaye ohun to ba yẹ ninu iwadii wọn.

Àkọlé fídíò,

Okunade Sijuwade: Ìfẹ́ tí Sarun tó súnmọ́ Ooni jù láyé ní sí í ló sọ ọ́ di abọ́bakú- Adeye