Ondo government bans tippers and Quarry associations: Oní Típà tó bá ta yanrìn ní owó gọbọi yóò fojú winá òfin - Ijọba ìpínlẹ̀ Ondo

Ọkọ

Oríṣun àwòrán, other

Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe awọn yoo fi ṣikun ofin mu ẹnikẹni tabi ẹgbẹ to ba n ta yanri ni owo gọbọi ti awọn ko fọwọ si nipinlẹ naa.

Olubadamọran pataki si Gomina ipinlẹ ọhun lori akanṣe isẹ, Ọmọwe Doyin Odebowale lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba.

Ṣaaju ni Odebowale ti kọkọ paṣẹ pe ki awọn ẹgbẹ naa da iye owo ti wọn n ta yanri pada si iye to wa tẹlẹ dipo owo gọbọi ti wọn fi kun, tabi ki wọn fi ipinlẹ ọhjun silẹ ni kankan.

Aṣẹ yii jade lẹyin ti iroyin to sọ pe awọn ẹgbẹ oni Tipa naa sun iye owo ti wọn n ta yanri lati ₦25,000 si ₦60,000.

Odebowale ṣalaye fun BBC pe "Awọn eeyan wa maa jade si igboro, ẹni ti a gba mu pe o tapa si ohun ti sọ, a oo fi ọlọpa mu irufẹ ẹni bẹẹ, yoo si foju bale ẹjọ."

"Ileeṣẹ to n pa owo wọle fun ijọba nipinlẹ Ondo, iyẹn Board of Internal Revenue, ODBIR, nikan lo laṣẹ lati gbe gege le iye owo ti ẹnikẹni le maa gba lọwọ araalu, o si ni iye ti yoo wọ apo ijọba ninu rẹ."

Alabaṣiṣẹ gomina ọhun ni awọn ti kọkọ ke si ẹgbẹ awọn ni Tipa naa lati yi iye owo tuntu naa pada ṣugbọn wọn kọ jalẹ.

Àkọlé fídíò,

Yollywood movies: Gbajúmọ̀ òṣèré, Rose Odika ní aráàú, àjọ 'Censors board'

O ni "Olubadamọran pataki si gomina lori ọrọ to jọ mọ ẹgbẹ, ọgbẹni Dare Aragbaye, ti ba awọn eeyan naa sọrọ, ṣugbọn kaka ki wọn ṣe ohun ti ijọba n fẹ, ni ṣe ni wọn bẹrẹ si n da aṣoju gomina lẹkọọ bi ẹni ti ko mọ iṣẹ rẹ ni iṣẹ."

"Awa ni a wa ni ijọba, a kii ta yẹpẹ tabi yanri, ṣugbọn ẹnikẹni ko kan le dede ku giiri wa si ipinlẹ Ondo lati maa fi aye ni awọn araalu lara."

Ẹwẹ, nigba ti BBC kan si Aarẹ ẹgbẹ awọn oniyanri naa nipinlẹ Ondo, Oguntayo Emmanuel, o ṣalaye pe lootọ ni awọn ti ṣe ipade kan pẹlu ijọba lori ọrọ naa, ṣugbọn ipade naa ko yọri si rere nitori awọn mejeji ko fẹnu ko lori igbesẹ to kan.

O fi kun pe ijọba ko bun awọn gbọ ki wọn to gbe igbesẹ lati fun awọn ni gbedeke.

Emmanuel ṣalaye siwaju si pe inu iroyin ni awọn ti gbọ aṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo pe ki awọn da owo naa pada si iye to wa tẹlẹ tabi ki awọn fi ipinlẹ Ondo silẹ.

Ni ti igbesẹ to kan fun ẹgbẹ oniyanri ọhun, Emmanuel ni awọn yoo ṣe ipade pajawiri mii pẹlu ijọba laipẹ lati wa ọna abayọ si họwu-họwu naa.

Ìjọba gbẹ́sẹ̀lé iṣẹ́ ẹgbẹ́ àwọn awakọ̀ Típà àti oníkùsà ní ìpínlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, other

Gomina ipinlẹ Ondo Oluwarotimi Akeredolu ti paṣẹ pe ko si aaye fun ẹgbẹ awọn awakọ Tipa ati kusa nitori owo gọbọi ti wọn gbe le yẹpẹ funfun laipẹ yii.

Lasiko ipade awọn oniroyin ti gomina pe, oluranlọwọ pataki lori isẹ akanse fun gomina Doyin Odebowale to soju fun gomina lo sọ bẹ

Lasiko to n kede iru inira ti awon to n ta yẹpẹ n ko ba ara ilu ni ipinlẹ Ondo, Ọdẹbọwale ni ijọba Ipinlẹ Ondo ko ni fi aaye gba ẹgbẹkẹgbẹ kankan lati maa lọ ara ilu lọwọ gba.

Ni bayii awọn ẹgbẹ awakọ yẹpẹ ikọle ti gbe owo yẹpẹ funfun lati ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira si ẹgbẹrunlọna ọgọta Naira fun loodu kan.

Ijọba ipinlẹ Ondo ti wa pasẹ ki wọn da owo naa pada si bi o ṣe wa tẹlẹ tabi ki wọn ṣetan lati fi ipinlẹ Ondo silẹ.

Oluranlọwọ pataki lori isẹ akanse fun gomina Doyin Ọdẹbọwale "Ìjọba ko ni fi aaye gba iwa irẹnijẹ mọ, bakan naa ni ko ni dẹkun lati fi ọwọ ofin mu ọmọ ẹgbẹ kankan to ba keti ikun si aṣẹ ijọba.

Àkọlé fídíò,

Yollywood movies: Gbajúmọ̀ òṣèré, Rose Odika ní aráàú, àjọ 'Censors board'

"Gomina Akeredolu ko ni faramọ awon awakọ akoyẹpẹ lati maa yan awon ara ilu jẹ, ati lati maa niwọn lara"

O fi kun pe ijọba ni agbara lati ri daju pe oun gbogun ti ohunkohun to ba le mu inira ba ara ilu.

"Ni pato a n sọ fun awọn to wa ni ibi ti wọn ti n fọ okuta ni ipinlẹ yii ti wọn si n pe ara wọn ni ọmọ egbẹ awọn oni Tipa lati fi ipinlẹ Ondo silẹ ni kiakia.