Crate challenge: Àwọn elétò ìlera sọ ewu tó wà nínú àṣà ìgbàlódé yìí

Crate

Oríṣun àwòrán, others

Ẹ ṣọ́ra fún "Crate challenge" nítorí ó lè sọ yín di èrò ilé ìwòsàn- àwọn dókítà kìlọ̀

Oniruru fidio lo ti gba oju opo ibaraẹnidọrẹ lori ayelujara kan nibi ti awọn eeyan ti n daṣa naa, paapaa lori Facebook, Instagram, ati TikTok.

Ninu Crate challenge ọhun ni awọn eeyan ti maa n gun ori ọpọ kireeti ẹlẹrindodo ti wọn maa n to bii piramiidi ti wọn a si maa gun awọn kireeti naa.

Àkọlé fídíò,

Rape survivor: Ìyá mi ni ń kò gbọdọ̀ sọ̀rs kí ilé má bà á dàrú- Oluwatobi Raji

Ṣugbọn pupọ ninu awọn to n daṣa igbalode yii lo maa n ṣubu lori rẹ ti wọn si maa n farapa.

Dokita kan ni fasiti ilu Kansas, l'Amẹrika, Chad Cannon ṣalaye pe ewu nla lo wa ninu aṣa tuntun ọhun.

Àkọlé fídíò,

Senato francis Fadahunsi: Ká ni wọ́n fún Buhari ladún mẹ́wàá sẹ́ypin ní, bóyá kò bá rí i ṣ

O ni "O ṣeeṣe ki eeyan ṣubu ko si gba ori mọlẹ, eyii to le sọ irufẹ ẹni bẹẹ di ero ile iwosan.

"Ti eeyan ba ṣubu le kireeti naa lori, o ṣeeṣe ki ọpa ẹyin rẹ kan ki o si ma le rin mọ."

Ileeṣẹ eto ilera kan to wa niluu Baltimore, l'Amẹrika yoii kan naa sọ fun awọn akọroyin pe awọn ile iwosan ti n kun akunfaya fun awọn eeyan to farapa lori "Crate challenge" naa.

Àkọlé fídíò,

Unijos students victims: Àwọn Fulani yabo 'hostel' wa, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Sọ́jà tí gómìnà ìpí

Ileeṣẹ naa sọ loju opo Twitter rẹ pe "Gbogbo ile iwosan lo ti kun fun awọn to n baa run Covid-19 finran, nitori naa ki o to darapọ mọ wọn lati daṣa Crate challenge, yẹ ile iwosan to wa ni ayika rẹ wo boya ibunsun ti wọn yoo gbe ọ si wa nibẹ."

Yatọ si Crate challenge to gbode kan lasiko yii, oniruru aṣa bẹẹ lo ti waye ṣaaju bii "Ice bucket challenge, silhouette challenge" ati "don't leave me challenge."