Mohammed Fawehinmi's burial: Òní ni èto ìsìnkú Mohammed ọmọ Gani Fawehinmi ní Akure

Awọn ibatan oloogbe

Pooropo lomije n ṣan loju awọn ero to bawọn peju sibi ti ara Mohammed Fawehinmi, to jẹ akọbi oloogbe ajafẹtọ ọmọniyan, Gani Fawehinmi, ti wọ kaa ilẹ sun nilu Ondo to jẹ ilu abinibi rẹ nipinlẹ Ondo.

Ara oloogbe ọun ni wọn bo mọlẹ lẹgbẹ aye ti wọn sinku baba ati iya-baba rẹ si nile oloogbe Gani Fawehinmi nipinlẹ Ondo.

Gomina ana nipinlẹ Ondo, Dokita Olusegun Mimiko ati alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu National Conscience Party, Tanko Yinusa, lo ṣaaju awọn eekan ilu, to fi mọ awọn ajafẹtọ ọmọniyan loriṣiriṣi, paapaa julọ awọn ọmọ igbimọ to n daabo bo ẹtọ taa mọ si CDHR nibi isinku naa.

Àkọlé àwòrán,

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ondo, Segun Mimiko darapọ mọ wọn nibi eto isinku naa

Ninu iwaasu rẹ, Alufa Robert Steven juwe oloogbe Mohammed Fawehinmi bi ẹni to nifẹ Ọlọrun, to korira titẹ ẹtọ araalu mọlẹ, to si tun sa gbogbo ipa rẹ lati ṣe igbesoke awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ.

Dokita Olusegun Mimiko wipe oloogbe naa lo ko ipa tirẹ lati ripe idajọ ododo fẹsẹ rinlẹ lawujọ, o si ṣee ladura pe ki Ọlọrun tẹẹ safẹfẹ rere.

Idiat Fawehinmi, to jẹ aburo Mohammed lo n wami loju nibi wọn ṣe sọ ara oloogbe naa kalẹ sinu saare, to si juwe ẹgbọn rẹ bii akanda ẹda.

Ṣaaju ki wọn too sin Mohammed ni awọn ọbakan rẹ, awọn ẹbi ati awọn ọmọ igbimọ CDHR ti yipo posi oloogbe naa lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un.

Oloogbe Mohammed Fawehinmi to jẹ ọmọ ọdun mejilelaadọta lo dagbere faye lọjọ kọkanlala oṣu kẹjọ ọdun yi lẹyin to lugbadi arun Covid-19.

Gbogbo eto ti to silẹ nipinlẹ Ondo bayii lati sinku oloogbe Mohammed Fawehinmi to jẹ ọmọ Gani Fawehinmi.'O dùn mí pé Gani kò sí láyé láti gba GCON'

Ajakalẹ arun coronavirus lo ṣe iku pa ajijangbara naa.

Lana ni wọn ti kọkọ sẹ alẹ ọjọ ẹyẹ fun oloogbe naa nile ijọsin Archbishop Vining Cathedral ni Ikeja ni ilu Eko.

Ninu atẹjade ti mọlẹbi oloogbe fi sita ni wọn ti kilọ pe ki koowa lasiko itankalẹ ajakalẹ arun coronavirus yii.

Àkọlé fídíò,

Muhammed Fawẹ̀hinmi: Bàbà mi yóò dunú níbi tó bá wà báyìí

Mohammed Fawehinmi jade laye lẹni ọdun mejilelaadọta.

O jẹ agbajẹrọ bii baba rẹ.

Àkọlé fídíò,

Ondo Jos clash: Èmi nìkan ló padà dé nínú àwa márùn ún tí a jọ lọ ìpàdé àdúrà ní Jos- Bell

O kawe nilu Oba, leyin naa lo gba oye LLB ni 1991, 1998.

Oun ni oludari ileeṣẹ Mohammed Fawehinmi's Chambers; Director, Nigerian Law Publications Limited.

Lodun 2003 lo ni ijamba ọkọ to kan eegun ẹyin rẹ to si di ero ori kẹkẹ.

Àkọlé fídíò,

Rape survivor: Ìyá mi ni ń kò gbọdọ̀ sọ̀rs kí ilé má bà á dàrú- Oluwatobi Raji